Ẹ jẹ́ kí n san N200,000 owó ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ mi fun yín, kí n sì máa lọ sílé – Bobrisky bẹ kóòtù

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/ Instagram

Lẹyin ti iroyin jade pe Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ (Bobrisky), pin aga fun ọgba ẹwọn to wa l’Ekoo to si tun pe ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun, ọkunrin to n mura bii obinrin naa ti bẹ kootu pe ki wọn jẹ koun san ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000) bii owo itanran, koun si maa lọ sile oun.

Ninu iwe ìpẹ̀jọ́ kan ti lọọya rẹ, Bimbọ Kusanu, kọ lorukọ Bobrisky, lo ti ni ki wọn jẹ koun san 50,000 fun ẹsun kọọkan toun jẹbi rẹ.

Bobrisky ṣalaye pe bo ṣe jẹ pe mẹrin lẹsun ọhun, 200,000 lo jẹ toun yoo san niyẹn.

O wa rọ kootu pe ki wọn jẹ koun fowo naa tan ọran kikan owo naira labuku toun da lode ìfilọ́lẹ̀ sinima Ẹniọla Ajao, ti wọn tori rẹ mu oun.

Ẹ o ranti pe funra Bobrisky lo ni oun jẹbi awọn ẹsun mẹrin naa nigba ti wọn gbọ ẹjọ rẹ l’Ekoo lọjọ karun-un oṣu kẹrin 2024 yii.

Adajọ Abimbọla Awogboro wa ran lẹwọn oṣu mẹfa lai fi aaye owo itanran silẹ fun un.

Ọkunrin to maa n mura bii obinrin, Idris Olanrewaju Okuneye, lo pe ẹjọ kotẹmilọrun naa tako ẹwọn oṣu mẹfa ti ile ẹjọ da fun lẹyin to jẹbi ẹsun titabuku owo naira.

Idris, ti ọpọ mọ si Bobrisky, lo pe ẹjọ naa lati ọwọ agbẹjọro rẹ, Bimbo Kusanu, pe ki ile ẹjọ yi idajọ ẹwọn to fun oun pda, ko si fun oun lanfani lati san owo itanra dipo ẹwọn.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni adajọ Abimbola Awogboro ti ile ẹjọ giga ilu Eko ṣedajọ ẹwọn oṣu mẹfa lai si anfani lati san owo itanran kankan fun Bobsirky lẹyin to jẹbi ẹsun titabuku owo naira.

Nigba to n dajọ ọhun, adajọ naa ni idajọ naa yoo kọ awọn araalu to ba fẹ maa wu irufẹ iwa bẹẹ lọgbọn.

“Ile ẹjọ fun mi ni ijiya to pọ julọ fun ẹsẹ ti mo ṣẹ tori n ko ni akọsilẹ kankan tẹ́lẹ̀ bii arufin”

Ṣaaju idajọ yii lọjọ karun un, oṣu Kẹrin yii kan naa ni ọdaran ọhun ti kọkọ sọ pe oun jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan oun.

Ninu iwe ipẹjọ kotẹmilọrun rẹ, ọdaran naa sọ pe ile ẹjọ fun oun ni ijiya to pọ julọ fun ẹsẹ ti oun ṣẹ bo tilẹ jẹ pe oun ko ni akọsilẹ kankan ṣaaju iṣelẹ naa gẹgẹ bii arufin.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, idajọ ọhun waye lai si oju aanu kankan fun oun, eyii ti ko si ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin Administration of Criminal Justice, ACJA, ti orilẹede Naijiria.

O fi kun pe adajọ naa ko tun wo ti pe oun ko fi akoko ile ẹjọ ṣofo latari bi oun ṣe tete sọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Bobrisky pín àga ọ̀fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó tún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Bobrisky fi aga ta ọgba ẹwọn lọrẹ

Ẹwẹ, laarin nnkan bii ọsẹ meji pere lọgba ẹwọn, iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe Bobrisky ti fi awọn aga kan ta ọgba ẹwọn Kirikiri to wa lọrẹ.

Ninu aworan aga naa to gba ori ayelujara, wọn kọ akọle “si ileeṣẹ ọgba ẹwọn Naijiria lati ọwọ idris Okuneye Bobrisky” si lara.

Iroyin to gba igboro nipa awọn aga naa ni pe o wa fun agbegbe ti awọn alejo yoo maa joko si lọgba ẹwọn naa.