Aisha Yesufu kó ọ̀rọ̀ Ooni dànù, ó ní ohun tó kàn kọ́ ni Ọòni fẹ́ lọ ṣe ní ìpèbí

Ooni ti Ile Ife n wọ Ipebi lọ laarin ero

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife

Lọjọ Aje ni iroyin jade pe Ọọni ile Ife, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji ti wọ ipebi fun ọjọ meje, gẹgẹ bi ara eto ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to maa n waye ni ọdọọdun.

Ooni, ninu ọrọ to fi ransẹ si araalu, ko to wọ ipebi lọ fun ọjọ meje salaye pe, ara ohun ti oun yoo ṣe lasiko naa ni lati gbadura ki Eledumare fọwọkan awọn oloṣelu ati adari gbogbo ninu.

Amọsa, ọrọ naa ti n fa oniruru ariyanjiyan laarin awọn ọmọ Naijiria. Lara awọn to ti sọrọ lori rẹ ni eekan ajafẹtọ araalu ni Naijiria, arabinrin Aisha Yesufu; ẹni to ni awada nla lọrọ naa jẹ fun oun nigba ti oun gbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni kawọn ómọ Naijiria yee reti ki Olorun wa ba wọn ṣe ohun ti awọn funra wọn le ṣe.

Loju Aisha Yesufu, Olorun ti ṣe eyi to ju ninu ọrọ nipa fifun wa ni anfani ati agbara lati dibo yan awọn aṣiwaju rere, sibẹ ọpọlọpọ ni kii lo agbara naa.

Pẹlu bi eto idibo apapọ ti ọdun 2023 se n bọ lọna bayii, o ni ki awọn ọmọ Naijiria lo anfani ati agbara naa lo ja julọ.

Amin iyasọtọ kan

Ẹ wo ohun tí Ooni yóò ṣe fáwọn olóṣèlú bó se wọ ìpèbí lọ fọ́dún Ọlọ́jọ́

Ooni Adeyeye Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife Facebook

Gẹgẹ bi ara igbesẹ fun ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ ti Ọdun yii, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Enitan Ogunwusi, Ọjaja keji ti wọ ipebi lọ lọjọ Aiku, nibi ti yoo wa fun ọjọ meje.

Itumọ ọdun ọlọjọ ni ọjọ ti ọjọ kọkọ bẹrẹ si ni jẹ ọjọ. Iyẹn ni pe ọjọ ti ojumọ kọkọ mọ lorilẹ aye.

Ninu iṣẹṣe ilu Ile Ifẹ, ọdun ọlọjọ ni wọn ya sọtọ lati ṣe ayajọ ọjọ ti Olodumare kọkọ da ile aye.

Ninu ọrọ rẹ ki o to wọ inu ipebi lọ Ọọni Ogunwusi ni ko si ohun meji ti oun nilo lati ṣe ninu ipebi ọlọjọ meje naa ju gbigba adura fun idagbasoke orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori ọba alade naa ni bi awọn ọmọ Naijiria ba woye daadaa, ọpẹ lo yẹ Naijiria paapaa pẹlu ajakalẹ arun COVID-19 to gbode lagbaye ṣugbọn ti ọṣẹ rẹ ṣu n mọ niwọnba ni Naijiria.

O ni sibẹ awọn adari ko gbọdọ sinmi lati rii pe ignayegbadun awọn araalu jẹ wọn logun. Ọọni Ogunwusi fi kun un pe idi gan niyi ti oun yoo fi lo ọjọ kẹfa ninu ipebi lati gbadura fawọn aṣiwaju ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Wiwọ ipebi ṣaaju ọdun ọlọjọ ṣe pataki pupọ, idi si niyi ti mi o le fi ṣere rara nitori ajogunba lọwọ awọn baba nka mi lati ẹgbẹkẹgbẹ ọdun sẹyin ni.”

Bakan naa lo fi kun pe oun yoo lo asiko naa lati gbadura si Eledumare ko fọwọ tọ awọn oloṣelu lọkan ki wọn lee dẹkun fifi aye araalu ta keke, ki wọn si lee maa tẹti si awon ohun gbogbo to n dun araalu lọkan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ