Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná – Oríadé kan figbe ta

Ile ti wọn jo nina

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Agbalagba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹ itan sare nitori aile sọrọ ni ibẹrẹ nnkan buruku.

Ọba alaye kan, Domini Yahaya ti ke gbajare fun gbogbo agbaye pe ikọlu awọn afurasi Fulani ti gba ẹmi aadọta eeyan, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ pẹlu.

Ọba alaye naa naa to wa lagbegbe Zango-Kataf ni guusu Kaduna salaye pe o tun le ni ile bii ọtalerugba o din mẹfa ti wọn ti jo kanlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn eeyan ti wọn ni awọn afurasi Fulani naa n kọlu ni alaboyun ati awọn ọmọ wẹwẹ, ti wsn si tun ba sọọsi meje jẹ kanlẹ pẹlu.

Ọba alaye naa, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Kaduna lọjọ Aje wa n kaya soke nipa bi ipaniyan ọlọgọọrọ yii se n waye lai si ẹni to mu wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni wọn ti gba akoso abule oun, ti ikọlu ojoojumọ naa si ti de gongo, eyi to le ru ibinu araalu soke kọja sisọ.

O fikun pe nitori ikọlu naa, ọpọ awọn ara abule naa ti wọn jẹ agbẹ, lo ti sa kuro lori ilẹ wọn lai le da oko mọ, to si le ni ẹgbẹrun mẹẹdogun araalu ti ko nile lori mọ.

Ọba Yahaya wa rawọ ẹbẹ sawọn agbofinro lati tete wa ọna dẹkun ikọlu ojoojumọ ọhun, eyi to le sokunfa rogbodiyan nla.

Amin iyasọtọ kan

Jonathan, má yẹ̀yẹ́ ara rẹ láti díje ìbò ààrẹ 2023 – Ọ̀gá ẹgbẹ́ àwọn gómìnà kìlọ̀

Aarẹ ana Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Goodluck Jonathan

Lẹyin ahesọ ọrọ ti gbalẹ kan pe aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan n gbero lati dije ninu ibo aarẹ ọdun 2023, ikilọ ti jade fun aarẹ ana orilẹede Naijiria bayii o.

Ọga agba ẹgbẹ awọn onilọsiwaju, Progressive Governors’ Forum (PGF), Ọmọwe Salihu Lukman ti kilọ fun Jonathan pe ko maa yẹyẹ ara rẹ nipa didije ninu ibo aarẹ ọdun 2023.

Ọmọwe Lukman ni afaimọ ki Jonathan ma ba orukọ rere to ti ni tẹlẹ jẹ to ba le dupo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati igba ti eto idibo gomina ipinlẹ Bayelsa ti waye lọdun 2019 nibi ti Jonathan ti ran oludije gomina APC, David Lyon lọwọ lati jawe olubori ni ọpọ ti n sọ pe o n sẹ ajọsẹpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC loke.

Awọn kan tiẹ tun sọ pe adehun ti Jonathan ṣe APC ni pe wọn yoo fun oun ni anfani lati dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọmọwe Lukman beere pe bawo lo maa ṣe ri ti Jonathan ba darapọ mọ APC ṣugbọn ti wọn ko fun ni iyọnda lati dupo aarẹ lọdun 2023.

”Ọrọ ibo aarẹ ọdun 2023 kọ lo yẹ kawọn eeyan maa sọ nipa Jonathan.

Ọrọ bi Jonathan ṣe gba pe oun fidi rẹmi ninu ọdun 2015 ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi wọle lo yẹ ki a maa sọ nipa Jonathan.

Nitori naa, ko yẹ ki ẹgbẹ oṣelu kankan ti Jonathan lati lọ dupo aarẹ, bi bẹẹ kọọ, wọn maa ba orukọ rẹ jẹ.

Ẹwẹ, iroyin sọ pe gomina ipinlẹ Ebonyi, Dave Umahi ati Ben Ayade ti Cross River to ṣẹṣẹ fi PDP silẹ lọ APC n gbero lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.