A tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà; èpo bẹntiról ń bọ̀ wá di ọ̀pọ̀ – Ọ̀gá àgbà NNPC

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Alaga Ajọ epo bẹntirol lorilẹede Naijiria, NNPC ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori ọwọngogo epo bẹntirol to gbode kan.

Adari ajọ NNPC, Mele Kolo Kyari fi idi rẹ mulẹ fun BBC pe iṣoro naa yoo dopin laipẹ.

Mele Kyari ni opin yoo de ba ọwọngogo epo bẹntirol laipẹ paapaa ni awọn ilu nla lorilẹede Naijiria.

Ipenija ọwọngogo epo bẹntirol to n koju awọn eniyan ti bẹrẹ lati ọdun to kọja, ti ko si si aridaju pe yoo dẹkun ki idibo gbogboogbo to waye ni oṣu keji, ọdun 2023.

Amọ, Mele Kyari ni opin yoo de ba ọwọngogo epo bẹntirol ni aarin ọjọ meji si isinyii, ti yoo si rọrun fun awọn eniyan lati ra epo.

Bakan naa lo fikun un pe awọn n gbe igbesẹ ti yoo fopin si ọwọngogo epo bẹntirol naa.

Kilo faa ti ọwọngogo epo ṣe peleke si ni Naijiria?

Adari ileeṣẹ to n risi epo bẹntirol naa ni gbogbo igba ti aigbọraẹniye ba ti waye laarin ijọba ati awọn agbepo ni ọwọngogo epo ma n wa.

Mele Kyari ni ọwọngogo epo naa kii ṣe pe nitori ko si epo amọ nitori awọn to n ko epo ọhun pamọ ni wọn n fa ọwọngogo.

Bakan naa lo ni iṣoro wa pẹlu pinpin epo kaakiri nitori awọn ọna ti ko dara to

O tun fikun un pe iye owo ti wọn n ta epo lagbaye pẹlu nkan to fa ọwọngogo epo ọhun.

Mele ni nitori ayipada to ba iye ti wọn nta epo lagbaye lo mu ki awọn to n pin epo fi owo kun un amọ kii ṣe lati ọdọ NNPC.

Awọn ileepo miran n fi ọkanjuwa ta epo ni ọwọngogo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ileeṣẹ NNPC naa ni nkan miran ti awọn eniyan n koju ni bi awọn ileepo kan ṣe n fi wọbia ati ere ajẹju fi ta epo fun awọn eniyan.

Amọ o ni ẹka ileeṣẹ naa to n risi ọrọ iye ti wọn n ta epo ti bẹrẹ si ni ṣe ofintoto lati ri pe wọn ko ta epo ju iye to yẹ lọ.

O fikun un pe ni awọn ilu bii Abuja, awọn ẹṣọ agbofinro naa wa ni ṣẹpẹ lati ri pe wọn ko ta epo ju bi o ṣe yẹ lọ.

Ni akotan, wọn tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria pẹlu idaniloju pe ọwọngogo naa yoo dopin laipẹ.