Ṣé Damilola Faparusi yòó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti se oúnjẹ fún ọgọ́fà wákàtí?

Damilola Aparusi n dana

Arábìnrin Faparusi Damilola tí ó jé akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Fáṣítì ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Oye Ekiti, Ipinlẹ Ekiti, lo n gbinyanjú láti ṣe oúnjẹ fún ọgọ́fà wákàtí ni ilu Ilupeju Ekiti.

Arábìnrin Damilola bẹrẹ iṣẹ sise oúnjẹ fun ọgọ́fà wákàtí ni òwúrọ̀ ọjọ́ Jimọ ni inu ile kékeré tí kò ní ayé púpọ fún ọgọọrọ ènìyàn.

Akọroyin BBC Yoruba to ṣe abẹwo sì Ilupeju Ekiti ní ibí ti ere-ije ounjẹ sise fun wakati pupọ náà tí ń wáyé, ṣe àkíyèsí pé kò sí àwọn eleto ìlera pajawiri níkalẹ pẹ̀lú ètò àbò tó péye fún arábìnrin Damilola.

Damilola Faparusi

Yàtọ̀ sí pé arábìnrin Damilola je Aláṣè oúnjẹ, ó tú jẹ onkọtán, o n kọ orin àti alatuto ìwé kíkọ pẹ̀lú àwọn itakun rẹ lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ó tun jẹ alakitiyan ènìyàn tó já fafa, ti o ni itara fun ṣiṣe iwadii kikọ nipa awọn nkan tuntun.

Damilola lo tí kópa nínú ere-ije oúnjẹ ṣíṣe tí ìjọ Spirit Word Global Mission tẹlẹ pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ rẹ nínú ìjọ.

Awọn eeyan yii lo sì dáná oúnjẹ fún àwọn ọmọ ìjọ náà fún ogójì wákàtí lé diẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.

Nínú ará akitiyan rẹ ni ó ti ní ìpinnu pè ohun lè ṣe kọjá ọgọrun wákàtí oúnjẹ ṣíṣe tí Arábìnrin Hilda Baci ṣe kọjá ní ìpínlẹ̀ Èkó, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ ọgọ́fà wákàtí tírẹ ni Ipinlẹ Ekiti.

O ti ni anfani lati ṣe awọn oniruuru ounjẹ gẹgẹbi: irẹsi ati ẹwa, awọn ẹwa Aláṣèpọ̀, Semovita pẹlu ẹfọ riro, Ìyàn àti ọbẹ̀ ẹ̀gúsì, ìṣù aláṣèpò, spaghetti, pẹlu àwọn ọpọlọpọ ounjẹ aládùn ti o dara.

Damilola Faparusi

Lásìkò tí a ń kó ìròyìn jọ, ní Damilola tí ló kọjá ọgọ́ta wákàtí dídána oúnjẹ ṣíṣe láìdáwọ́ dúró.

Ọgọọrọ eeyan to wá wò Damilola gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nímọ̀ràn láti má fi ẹnu àtẹ́ lu igbiyanju ọdọmọbìnrin aláṣè naa, lati se ounjẹ fun wakati ọgọfa.