Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! – Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta

Oloogbe Timothy ati aworan mọlẹbi

Lẹyin ti ọwọ awọn agbofinro tẹ awọn afurasi to se iku pa arakurin Timothy Adegoke ni ile itura kan ni ilu Ile ife, awọn idile Adegoke ti kigbe sita pe awon afurasi ti n bere pe elo ni a fẹ gba.

Iroyin ti j ka mọ pe oludasile ile iwe giga fasiti Oduduwa University, Ọmọwe Ramon Adedoyin to si jẹ pe oun naa lo ni ile itura Hilton Hotel ti Timothy ku si.

Iyawo atawọn ọmọ Timothy

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iyawo oloogbe, Arabinrin Adegoke Bolatito Victoria, ninu ifọrọwerọ pẹlu ile iṣẹ́ BBC NEWS YORUBA lo fi ẹsun kan afurasi ti Ọlọpaa mu pe awọn kan lọ ba aburo ọkọ oun to maa n pe ni baba ọkọ ti wọn si n gbe igbese lati fun idile awọn ni owo ki wọn le yanju ọ̀rọ̀ naa lai pariwo sita. Amọ BBC Yoruba ko lee fidi eleyii mulẹ.

Ninu itara o ni, “wọn fi owo lọ baba ọkọ mi, ṣe owo le da ọkọ mi pada ni. Ẹyin ijoba ẹ ma wo wa niran, ẹyin ọmọ Naijiria ẹ dide iranlọwọ fun wa o!”

Iyawo Timothy ni awọn o lẹlomiran mọ ni idile Adegoke tori Timothy ni gbogbo awọn gbe ọkan le.

“Oun lo n bọ iya ati baba pẹlu awọn aburo rẹ. Ọmọ mẹta ni a bi fun ara wa, ṣe owo le da oro ti won da idile Adegoke duro? Lẹyin ti wọn pa ọkọ mi ni irinajo ti ko le wale mọ, ẹ gba mi ooo.”

Lafikun, Arabinrin Adegoke Bolatito Victoria ni ọ̀rọ̀ naa kii ṣe titẹ oju ọmọ eniyan mọlẹ nikan ṣugbọn pẹlu fifi ọpọlọpọ ọmọ orilẹede si ewu to le mu ẹmi lọ gẹgẹ bi o ṣe mu ẹmi ọkọ rẹ, Arakunrin Timothy Adegoke lọ.

Iya ati baba Timothy

Pẹlu omije ati ibanuje ọkan ni awon obi Timothy Adegoke, Baba Moses ati Mama Bose Adegoke ni awọn n rawọ ẹbẹ si ijọba lati ma jẹ ki iku ọmọ wọn lọ lai si idajọ ododo.

Mama Bose Adegoke ninu ọ̀rọ̀ rẹ ni ọkanlawọn ọmọ ni ọmọ awon jẹ ki iṣẹlẹ yii to ṣẹlẹ, ti iku rẹ si da ọpọlọpọ irinajo ru nitori Timothy ni o n gbọ bukata awọn ati awọn aburo r to fi mọ iyawo ati ọmọ mẹta.

Oloogbe Timothy ati Oludasilẹ ile itura to ku si

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ