Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá – Baba Ijesha

Baba Ijesa ati Pricess Comedia

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Emi kọ ni mo kọ gbogbo akọsilẹ ti ọlọpaa bere fun lọjọ ti wọn mu mi, koda wọn mu mi ni tipa tipa lati kọwọ bọ iwe naa ni – Baba Ijesa.

Ní ìtẹ̀síwájú igbẹjọ Baba Ijesha lórí ẹsun biba ọmọde lopọ ti wọn fi kan an, afurasi naa tún ti yọjú sílé ẹjọ lónìí.

Nibi igbelẹjọ náà to waye nile ẹjọ gíga tó wà niluu Eko, ni Baba Ijesha ti sọ pe wọn na òun nílùú bara nile Princess ki wọn to gbe oun lọ sí àgọ ọlọpaa nibi ti wọn ti fi ipa gba ọrọ silẹ lẹnu oun.

Ẹwẹ, ikọ olupẹjọ tun mu ẹlẹrìí mii wá, to jẹ ọlọpaa, wá síwájú ilé ẹjọ lati jẹri tako Baba Ijesha.

Ẹlẹri náà to jẹ obinrin, Omane Abigael sọ pé òun jẹ oṣiṣẹ ni agọ ọlọ́pàá tí wọn ti mu Baba Ijesha, ni ẹka tó n gbogun ti iwa ifipabanilopọ ati ẹsun ṣiṣe ọmọde baṣubaṣu.

Omane sọ pé òun gangan lo fi ṣikun ofin mu afurasi lẹyìn tí àwọn gba ipe ori ago pe o bá ọmọ tí ọrọ kan lopọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gẹgẹ bíi ohun tó sọ, afurasi ṣàlàyé bi ọrọ ṣe jẹ, tó sì jẹ́wọ́ pé lootọ ni òun ṣe ohun tí wọn fi ẹsùn rẹ kan oun.

Ọlọpaa náà sọ pe oun kọ ọrọ Baba Ijesha silẹ, lẹyìn náà ni òun fúnra rẹ fi ọwọ si ọrọ ọhun.

Ṣugbọn agbẹjọro Baba Ijesha, Babatunde Ogala sọ pé òun kọ ki ile ẹjọ gba ọrọ naa wọlé nítorí inú ìnira ni Baba Ijesha ti fi ọrọ naa lelẹ.

Omane ni, ṣe ni Baba Ijesha n gbọ bíi ewe oju omi nì àgọ́ àwọn, tó sì sọ pé òun kò ni joko sórí àga, lẹyìn náà ló joko silẹ ki wọn to gba ọrọ rẹ silẹ.

Ọlọpaa náà ni asọ Baba Ijesha ti ya nigba ti òun yóò mú lati ile Princess dé agọ awọn.

Leyin eyi ni wọn pe Baba Ijesha síwájú lati wa sọ tẹnu rẹ lórí ọrọ ti ọlọpaa, Omane sọ ṣaaju.

Baba Ijesha ni wọn lu oun nilu bara, wọn sì ya aṣọ òun kì wọn tó gbe oun lọ sí àgọ ọlọpaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni “Wọn kò ṣẹkẹṣẹkẹ sí mi lọwọ, won dé ọwọ mi sí ẹyin, awọn bíi mẹrin sì bẹrẹ sí n lu mu, Abigael kò sì ṣe ohunkohun nípa rẹ.”

“Ni kété ti mo de agọ ọlọpaa ni wọn ti mi mọ inu túbú.”

“Abigael ni ki n joko silẹ, o si bẹrẹ sí n kọ ọrọ ti mi o sọ silẹ, lẹyìn náà ló ní kí n tọwọ bọ ọrọ naa tí mo bá fẹ jáde kúrò nínu atimọle lọjọ náà lọhun.”

Baba Ijesha ni oun kọ ló sọ gbogbo ohun to wà nínú àkọsílẹ náà ti wọn mú wa siwaju adájọ, ṣugbọn ipa ni wọn fi mú òun láti tọwọ bọ ọrọ náà.”

Lẹyìn atotonu awọn agbẹjọro méjèjì, to fi mọ ẹlẹrii ati olujẹjọ, adajọ Oluwatoyin Taiwo ti sún ẹjọ náà sì ọjọ keji, oṣù Kejìlá, ọdún yìí.