Wo ohun tí Baba Ijesha sọ fún BBC níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó wáyé lónìí

Baba Ijesha

BBC Yorùbá: Kí lẹ ní láti sọ fún àwọn olólùfẹ́ yín lórí ẹ̀sùn tí wọ́n ti ń báa yín fi ẹ̀mí ṣọ́ yìí?

Baba Ijesha: Lórí ọ̀rọ̀ yìí, mi ò ní ọ̀rọ̀ kankan láti sọ…

Ni Ogunjọ oṣu kẹwaa, igbẹjọ Baba Ijesha ti tẹsiwaju nílé ẹjọ gíga to n gbọ ẹsun ifipabanilopo ti wọn fi kan niluu Eko.

Nibi igbẹjọ náà ni agbẹjọro ijoba ti fi fídíò kan hàn nile ẹjọ náà.

Ninu fidio ọhún ni onimọ nipa iwuwasi ọmọde, Bisi Àjàyí Kayode ti ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹlu ọmọ Princess, ti wọn sọ pé Baba Ijesha ba ni Ibalopọ.

Ọmọdebinrin náà ṣàlàyé bo ṣe mọ Baba Ijesha ati ohun to ṣẹlẹ láàrin àwọn méjèjì.

Gẹgẹ bíi ohun ti ọmọ náà sọ, nnkan bíi ọdún méje sẹyìn ni oun ti mọ Baba Ijesha, ọdún náà ló sì kọkọ fọwọ kan oun to sì sọ fún òun pé òun nífẹẹ oun gidi ṣugbọn ki oun ma ṣe jẹ ki eti mii gbọ.

Ọ so siwaju sí pé Baba Ijesha tún fọwọ kan oun ninu kẹrin ọdún yìí kì àkàrà to tu sepo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọmọ náà ni cartoon ni oun n wo ko to pe oun pe ki oun wa joko sí orí ẹsẹ rẹ, tó sì ni kí òun bọ pátá.

Gẹgẹ bíi oun to sọ, oun wa lori itan rẹ dùn ìgbà díẹ, lẹyìn náà ló dá atọ, tó sì ni kí òun lo wà aṣọ lati nu ara òun, ki oun to lọ sile iwẹ.

Ọmọ náà ni inú yara igbalejo ile awọn ni iṣẹlẹ naa ti wáyé, oun kò sí bùn ẹnikẹni gbọ.

Ọ tẹsiwaju pe “Ọjọ keji ọjọ náà lo pada wá lo ki kọkọrọ ọkọ sí idi mí tó sì tunt gbiyanju lati fi ẹnu kò mi lẹnu.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Amọ lọjọ ti asiri rẹ tu yìí, ọ sọ fún mi pé mo ti toju bọ, ọ si yẹ kí n ti máa ni ọrẹkunrin, ati pe oun ko ni gbà ki n ni ọrẹkunrin kankan nítorí òun lo ni mi.”

Ni gbogbo igba ti ọmọ náà n sàlàyé ọrọ naa, ṣe ni Princess ka ọwọ lori.

Ẹwẹ, agbẹjọro Baba Ijesha, Babatunde Ogala bi onimọ nípa iwuwasi ọmọde náà ni àwọn ibere kan láti fìdí rẹ múlẹ boya o dantọ lati bi ọmọ tí ọrọ naa kan ni awọn ibere to bere nipat Baba Okeshat ninu fídíò ọhun.

Agbẹjọro máa tún gbìyànjú láti mọ boya ododo ni oun ti omot naa sọ fún arabinrin Bisi Ajayi.

Igbẹjọ náà yóò máa tẹ̀síwájú lọla ode yii.