Wo bí Nkechi Blessing ṣe dákú rọngbọndan níbí ìsìnkú ìyá rẹ̀ l’Eko

Ọrọ ikẹdun Toyin si Nkechi

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham

Lọjọ Satide nibi ti gbajugbaja oṣere Nkechi Blessing-Sunday ti n ṣe eto isinku iya rẹ, oloogbe Gloria Sunday lo ti dede ṣubu wọọ silẹ.

Oṣerebinrin naa ti farasin loju opo ayelujara fun igba diẹ koda to pa awọn nkan to ti fi soju opo Instagram rẹ rẹ tabi yọ wọn kuro lati bu ọla fun iya rẹ to dagbere faye lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan.

Aworan meji pere lo wa loju opo Instagram Nkechi lọwọlọwọ to si jẹ pe ti iya rẹ nikan ni ati atjade kan to ti pere to ti gbadura pe “Ọlọrun ma jẹ ki iṣoro mi bo igbagbọ mi mọlẹ lorukọ Jesu… Amin”.

Amọ gẹgẹ bi wọn ṣe n sin oku iya rẹ lọjọ Abamẹta ọjọ Kẹrindinlogun ni ilu Eko nibi ti oun atawọn eeyan kan jọ wa lo ti dede daku to ṣubu lulẹ.

Ọpọlọpọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ Tiata, ẹbi atawọn ọrẹ rẹ lo peju sibi eto isinku iya rẹ ti wọn si ti n fi aworan ati fidio bi ohun gbogbo ṣe lọ sita.

Lara fidio naa ti wọn fi sita ni ọkan nigba ti awọn agboku n gbe posi iya rẹ jade ti Nkechi daku.

Fidio naa ṣafihan bi awọn mọlẹbi ati ọrẹ rẹ to wa nibẹ n gbiyanju lati jii dide pada.

Ṣe ni Nkechi Blessing ti irẹpọ aarin oun ati iya rẹ wọ ara gidi gan gẹgẹ bo ṣe sọ n sọkun pẹẹrẹpẹrẹ lori posi iya rẹ to si n tun n kede ifẹ rẹ fun Mama Nkechi bo ṣe maa n pee.

“Ẹ fi mi silẹ, ẹ ma sọ fun mi pe ki n ma sọkun o, Mama, fi mi silẹ, mo ti ro wipe ẹ maa ji dide lonii.

Ẹ jọwọ ẹ ma jẹ kawọn eeyan ibi yii ri mi mu, ẹ jọwọ ẹ maa ṣọ emi atawọn aburo mi o…” Eyi ni awọn ọrọ ti oṣere Nkechi Blessing n sọ bo ṣe n sọkun.

Ọkan lara awọn ọrẹ rẹ to tun jẹ akẹgbẹ rẹ, toyin Abraham fi fidio naa sita to si kọ ọrọ itunu ranṣẹ si Nkechi pe bo tilẹ jẹ pe oun naa ti la iru ri kọja ri, ko sẹni to lee ṣalaye ilakọja tirẹ amọ ko jẹ bẹrẹ si ni kuro lọkan rẹ eyi tii ṣe igbesẹ akọkọ.

Ninu awọn fidio mii la ti pada rii ti oṣere naa n ba awọn alabayọ rẹ jo papọ bii Toyin Abraham, Iyabo Ojo, Woli Arole, Pretty Mike ati bẹẹ lọ.

Nkechi ti ṣaaju sọ nipa bi oun ṣe ti kọ ọrọ kan sita ri pe oun lo maa n ṣe fawọn eeyan ko sẹni to maa n ṣe fun oun. Amọ lasiko ti iya rẹ ku yii o n dupẹ lọwọ awọn to dide fun un to si tun ni ọpẹ mii n bọ.

“Mi o tilẹ na owo kankan bayii to jẹ temi. Kii ṣe ti pe mo ni o amọ Ọlọrun a ya gbogbo yin lẹnu pẹlu ibukun

Fun igba diẹ bayii ni nkechi Blessing ti n ni oniruuru fa ki n faa ọrọ lori ayelujara pẹlu awn oṣere akẹgbẹ rẹ mii.