Tùẹ̀, èsì yín ò jẹ wá! Ohun mẹ́rin tuntun táa ń bèrè lọ́wọ́ Òṣèré Odunlade àti TAMPAN rèé bí bẹ́ẹ̀ kọ́ – THURIST

Aworan Fiimu Odunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola

” A fẹ ki wọn fi iya jẹ Oṣere Odunlade Adekola gẹgẹ bo ṣe wa ninu ilana ofin ẹgbẹ TAMPAN”.

Ẹgbẹ ajafẹtọ ẹsin Musulumi kan, Ta’awunu Human Rights of Nigeria ti tun wu ọrọ irunu mii sita lorii fiimu ti gbajugbaja oṣere, Odunlade Adekola gbe jade eyi ti wọn ni o tabuku awọn obinrin ẹlẹsin Islam.

Nibayii wọn tun ti lọ́ ẹsun ọhun mọ obinrin to ko ipa Ẹlẹhaa ninu fiimu naa, Arabinrin Olufunmi Bakare.

Wọn yari pe Odunlade mọọmọ ṣe fiimu naa jade lati tabuku awọn obinrin to n boju ninu ẹsin Islam ni to tun ni ibi ti Ẹlẹhaa ọhun n wọ motọ lọ ninu fiimu naa, Iyanna Ọrun, ko sibi to n jẹ bẹẹ nibikibi ni Naijiria.

Ẹgbẹ THURIST ni awọn ti gbọ oniruuru ọrọ ti awọn eeyan n sọ kiri nigba ti awọn fi aidunu han si nkan ti oṣere naa ṣe.

“A fẹ jẹ ki gbogbo eniyan mọ pe a ti gba ọpọlọpọ esi ati ipe ti awọn eeyan fẹ fi ṣi awọn araalu lọkan pe gbajumọ oṣere nni Odunlade Adekola ko ipa ribiribi ninu fiimu naa oun naa si ni o ni fiimu naa.

A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe a ni ikọ ọtẹlẹmuyẹ tiwa to maa n fun wa ni iroyin kikakia to si ṣee gbagbọ torinaa a o le jẹ ki ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ ka lroi ayelujara to ṣẹ jade lẹyin taa fẹsun kan wa gbona ju ohun taa n sọ lọ. A ti fi ẹsun kan to si jẹ ootọ, a ṣi n duro lori ọrọ wa”.

Wọn ni oṣere naa ba wa gbagbọ pe ẹsun odi lawọn fi kan an, ko jade wa lati sọrọ ni gbangba.

“Bakan naa, a fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ni ibamu pẹlu jija fẹtọ ẹni ni ẹgbẹ yii fi tun fi ẹsun kan Arabinrin Olufunmi Bakare pẹlu Ọgbẹni Odunlade Adekola ati ẹgbẹ TAMPAN to n ṣakoso awọn oṣere fiimu Yoruba pe wọn kuna lati yẹ fiimu ọhun wo tabi fofin de iru rẹ”.

Wọn ni awọn da obinrin naa ati Odunlade papọ ninu ẹsun yii tori pe o ṣeeṣe ki Odunlade ti beere lati lo obinrin naa Olufunmi ki ọwọ ofin ma baa muu.

“Amọ a fi n daa yin loju pe gbogbo ẹnikẹni to ba kopa ninu ere naa yala ipa kekere tabi nla, Musulumi ni tabi kii ṣe Musulumi lai fi ti ipo wọn ṣe la o ko pọ bi asiko ba to tori inu bi wa gidi fun ọna ti wọn gba ṣafihan Ẹlẹhaa naa.

Fun idi eyi, awọn koko mẹrin ti a n beere fun laarin ẹgbẹ TAMPAN ati Ọgbẹni Odunlade Adekola niwọnyii:

1. Dida gbogbo ipele to ba ku ninu sinima “Iku Ni” duro ki wọn si ko o kuro lori gbogbo awọn oju opo ayelujara to ba wa to fi mọ Youtube laarin ọjọ meje.

2. fifi iya to tọ jẹ ẹni to gbe fiimu naa jade, odunlade Adekola ni ibamu pẹlu ohun ti ofin ati alakalẹ ẹgbẹ TAMPAN sọ.

3. Ṣiṣe ayẹwo fiimu gbogbo awọn oṣere to ba tun fẹ gbe iru nkan bayii jade.

4. Ki wọn pọn ọn ni dandan fun oṣere to ni fiimu naa lati tuba fun ẹgbẹ Musulumi ọhun fun iru fiimu to gbe jade yii nipasẹ ilana ti tile toko yoo rii.

“Inu wa dun pe BBC Yoruba jẹ ka mọ pe aarẹ ẹgbẹ TAMPAN Ọgbẹni Bolaji Amusan ti a mọ si Mr Latin ti ni oun yoo to sọrọ sita lori ipẹjọ wa yii”.

Wọn ni awọn fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ipẹjọ awn ko i ku lori ọrọ yii o pe o ṣi wa laaye am pabanbari ohun tawọn fẹ ni ki ati Ọgbẹni Odunlade ati TAMPAN tọrọ aforijin ni gbangba laarin ọjọ meje.

Eyi waye ninu atẹjade ti Agbẹjọro AbdulHakeem Abdul-Lateef ati Agbẹjọro Abdulsalama Abdul Fattah jọ fọwọ si ti wọn si ni bi Odunlade ati TAMPAN ko ba ṣe nkan tawọn n fẹ, awọn yoo gbe igbesẹ to lagbara ti awọn o si ni sọ bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ