Tani yóò lulẹ̀ nínú Adeleke àti Oyetola l’Ọ́ṣun? Òní ni iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò dájọ̀

Oyetọla ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, other

Loni ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo gbe idajọ kalẹ lori idije sipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun.

Ile ẹjọ kọtẹmilọrun lorilẹede Naijiria, eyi to fikalẹ si ilu Abuja yoo sọ boya gomina Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP tabi gomina ana, Gboyega Oyetọla ni gomina ti ilu dibo yan nipinlẹ naa.

Gomina Adeleke to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun lọdun 2022 yẹ aga mọ Gboyega Oyetọla to jẹ gomina ipinlẹ naa laarin ọdun 2018 si 2022 nidi.

Bawo ni ọrọ ṣe bẹrẹ?

Idibo si ipo gomina nipinlẹ Ọṣun waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2022. Lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keje ọdun 2022 ni ajọ INEC kede Ademọla Adeleke to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi gomina ati olubori ibo naa.

Adeleke moke ni ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ninu ijọba ibilẹ Ọgbọn to wa ni ipinlẹ naa.

Gboyega Oyetọla to jẹ oludije APC moke ni ijọba ibilẹ mẹtala.

Lapapọ, Adeleke ko ibo ẹgbẹrun mẹtalenirinwo ati ọọdunrin o le aadọrin ati ẹyọkan (403,371), Oyetọla si ko ibo ẹgbẹrun lọna ọọdun o le marundinlaadọrin ati mẹtadinlọgbọn (375, 027)

Adeleke nibi eto ijẹjẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke/twitter

Pẹlu esi yii, Ademọla Adeleke yẹ aga mọ Gboyega Oyetọla, oludije ti APC to jẹ gomina lasiko naa nidi.

Ẹgbẹ oṣelu marundinlogun ati Oludije wọn lo kopa ninu eto idibo naa lara awọn ti Kẹhinde Munirudeen Atanda pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹwaa ati mẹrinlelọgọrun (10,104), Akin Ogunbiyi ti ẹgbẹ oṣelu Accord wa pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹrin o le ẹẹdẹgbẹta ati mẹrinla(4,514), igbakeji olori ileegbimọ aṣojuṣofin nigbakan ri, Lasun Yusuf ti ẹgbẹ oṣelu LP to ni ibo ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹrin o le mọkandinlọgbọn (2, 729) ati Goke Omigbọdun ti ẹgbẹ oṣelu SDP pẹlu ibo ẹẹdẹgbẹta o le marundinlogun(515).

Ile ẹjọ to gbọ awuyewuye idibo kede Oyetọla gẹgẹ bi gomina dipo Adeleke

Lẹyin ikede esi idibo ni Oyetọla gba ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo gomina nipinlẹ Ọṣun lọ lati tako esi ibo ti ajọ INEC kede.

Lọjọ karun oṣu kẹjọ ọdun 2022 ni Oyetola gba ile ẹjọ lọ nilu Osogbo lati wọgile esi to kede Adeleke gẹgẹ bi olubori ibo naa. O ni ọpọ kotọ lo waye lasiko ibo ọhun ati pe Adeleke ko lẹtọ lati dije nitori “ayederu iwe ẹri lo fi dije”.

Adegboyega Oyetọla, gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, adegboyega oyetola/twitter

Bakan naa lo rọ ile ẹjọ naa pe ko kede oun gẹgẹ bi ẹni gan an ti ilu dibo yan ni ipinlẹ Ọṣun.

Adeleke naa ko igbimọ agbẹjọro mejilelaadọta jọ lati gbẹjọ rẹ ro, Oyetọla ṣa aadọta agbẹjọro jọ lati gbọ ẹjọ tirẹ.

Lẹyin ọpọ atotonu ati awijare, igbimọ adajọ mẹta ile ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ igbimọ ọhun.

Labẹ idari onidajọ, Tetse Kume pari igbẹjọ lọjọ kẹtala oṣu kini ọdun 2023 ki o to fi idajọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kini kan naa.

Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ to gbọ awuyewuye esi ibo gomina nipinlẹ Ọṣun naa wọgile esi ibo to gbe Adeleke wọle gẹgẹ bii gomina.

Ile ẹjọ naa ni INEC ko tẹle iwe ofin Naijiria ati iwe ofin eto idibo Naijiria.