SARs bọ́ mi sí ìhòòhò lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn tí mi ò mọ̀dí rẹ̀ – Bimbo Akinsanya

Bimbo Akinsanya

Oríṣun àwòrán, Bimbo Akinsanya

Gbajugbaja oṣere tiata, Bimbo Akinsanya ti salaye ohun to fa rogbodiyan laarin rẹ ati ileeṣẹ ọlọpaa, eyi to mu dero ileẹjọ fun ẹsun pe o fẹ ṣeku pa eeyan kan.

Ninu ifọrọwerọ rẹ kan ti oju opo Ojopagogo TV gbe jade lori ayelujara, Akinsanya ni isẹlẹ naa lo jẹ ohun manigbagbe to ma n ba oun lọkan jẹ ni ọpọ igba.

Akinsanya ni iriri oun pẹlu awọn ọlọpaa SARs ati iha ti awọn akọroyin kan fi gbe iroyin naa jade, dun oun pupọ.

Ki lo de ti Bimbo Akinsanya fi dero atimọle lori ẹsun ipaniyan?

Gẹgẹ bii Bimbo Akinsanye ṣe sọ, o ni arabinrin kan to jẹ olusọ aguntan, ti wọn mu ile ijọsin si ẹgbẹ ile Baba Akinsanya ni agbegbe Akowonjọ ni ijọba ibilẹ Alimosho niluu Eko, lo mu ẹjọ oun lọ si ọdọ awọn Ọlọpaa SARs pe oun ran awọn apaniyan lati wa pa nile ijọsin.

“Inu awẹ ni mo wa lọjọ naa ti awọn ọlọpaa de. Gbogbo wa ni adugbo naa ni a mọ pe oniwa ijangbọn ni obinrin naa.

“Ariwo ile ijọsin rẹ pọ fun gbogbo wa ni adugbo, mo si gbọ pe ọpọ igba ni wọn ti lọ fi ẹjọ obinrin naa sun lọdọ awọn ọlọpaa.

“Obinrin naa leri, o n ba awọn eeyan fa wahala ladugbo,

“Mo n wo fiimu lọwọ ni awọn ọlọpaa wọle wa mu mi mọ awọn eeyan to n dunkooko lati pa obinrin naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/the_bimboakisanya/

“Mo wa ni ahamọ ọlọpaa fun ọjọ mẹrin, ọpẹlọpẹ MC Oluomo atawọn eeyan mii to gba mi silẹ”

Akinsanya tẹsiwaju pe ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti Obinrin naa sọ fun awọn ọlopaa pe oun wọ ile ijọsin wa, ti obinrin naa si n ka si pe oun ni ki awọn apaniyan ṣeku pa.

O ni wọn kọkọ gbe oun lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ni Afonka, lati ibẹ, wọn tun gbe oun lọ si ileeṣẹ ọlọpaa SARs ni Ikeja.

“Mo wa ni agọ ọlọpaa fun odidi ọjọ mẹrin, ọpẹlọpẹ Ọlọrun, MC Olumo, Baba Sobulọ, Mattew Ididowo ati awọn iransẹ Ọlọrun miiran.

“Awọn ọlọpaa ni ki n bọra si ihoho loju ibọn, mo bọra ku sokoto nikan”

Akinsanya ni nigba ti oun de ọdọ awọn ọlọpaa SARs, ọlọpaa to wa nidi akoso ẹjọ naa ni dandan ni ki oun bọ gbogbo asọ oun silẹ.

O ni igba akọkọ ree ti oun yoo sọrọ naa sita.

“Asọ Jeans ati ẹwu kan ni mọ wọ, Ọga ọlọpaa ni ki n bọ silẹ, mo bọ ẹwu nitori wọn gbe ibọn dani.

“Wọn ni mo gbọdọ jẹwọ pe mo ran awọn apaniyan pe ki wọn ṣeku pa Obinrin naa.

“O ni ki bọ kọmu silẹ, mo bọ silẹ, mọ wa wo ọyan mi nilẹ.

“Ọga ọlọpaa tun ki n bọ sokoto mi ati pata mi silẹ ni alẹ.

“Wọn wa ni ti n ko ba jẹwọ, awọn ma yinbọn pa mi, Ọlọpaa yẹn n yinbọn lu ilẹ, ti afẹsi ibọn na si ba mi lẹsẹ.

“Mo pariwo, mo bu sẹkun, mo ni n ko mọ ohunkonu nipa ẹsun ti wọn fi kan mi yii, koda n ko mọ obinrin yẹn rara.

“Ẹjọ yii de ileẹjọ, ti Ọlọrun si pada gba gbogbo ogo.”

Ta ni Bimbo Akinsanya

Gbajugbaja oṣere tiata ni Bimbo Akinsanya, to ti kopa ninu ọpọlọpọ sinima agbelewo lorilẹede Naijria.

Wọn bi Bimbo Akinsanya ni agbegbe Ebutte Meta, niluu Eko, oun ni abikẹyin ninu ọmọ mẹfa ti awọn obi rẹ bi saye.

O bẹrẹ iwe ẹkọ alakọbẹrẹ ni Miss Peter Nursey and Primary School.

O tẹsiwaju lọ si Akowonjo Pramary School, lati ibẹ o lọ Girls High School ni agbegbe Agege niluu Eko.

Akinsanya jẹ akẹkọ jade ile ẹkọ gbogbo niṣe Poly niluu Iree nipinlẹ Osun, ko to tun morile Fasiti ipinlẹ Ogun.

A ko le sọ pato ọdun ti Akinsanya bẹrẹ si ni ṣe isẹ sinima sugbọn ninu ifọrọwerọ to ṣe ni aipẹ yii, o ni lati igba to ti wa ni ile ẹkọ gbogbo niṣe Poly ni o ti wu oun lati jẹ oṣere tiata.

O ni oun nifẹ lati maa wo awokọṣe awọn oṣere tiata bi Bimpe Adekola, Liz Benson ati Reginal Askia.

Gẹgẹ bi Akinsanya ṣe salaye, o ni oun pade gbajugbaja oṣerebinrin kan, to si mu oun lọ si ẹgbẹ osere tiata kan ti wọn n pe ni Odunfa caucus.

Akinsanya ni ibẹ ni oun ti pade ọpọlọpọ gbajugbaja oṣere tiata miiran, ti oun si darapọ mọ wọn.