Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ àwọn tó ń kó ìbọn wọ ìpínlẹ̀ Oyo lábẹ́ ìbòjú ìwọ́de Naira tuntun – Kọmísọ́nà ọlọ́pàá Oyo

Iwọde

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Adebọwale Williams sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn janduku kan to n ko nnkan ija oloro jọ ni ipinlẹ naa lati fi da wahala silẹ labẹ iboju iwọde tako ayipada owo ati ọwọngogo epo.

Kọmiṣọna ọlọpaa Williams sọ pe erongba awọn ẹgbẹ naa ni lati da ina wahala ati rogbodiyan silẹ lawọn agbegbe kan ni ilu Ibadan lasiko iwọde to n waye lori inira ọwọngogo epo ati ayipada owo naira tuntun.

Kọmiṣọna ọlọpaa naa ṣalaye eyi lasiko ipade apero lori eto abo nipinlẹ Ọyọ nibiti awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo nipinlẹ Ọyọ ti fikuluku pẹlu awọn adari banki apapọ CBN, ẹgbẹ awọn ontaja epo aladani, IPMAN, ẹgbẹ awọnto n ṣe owo POS, awọn olori ọlọja, awọn ọbalaye atawọn olori ẹsin gbogbo.

Kọmiṣọna ọlọpaa Adebọwale Williams sọ pe diẹ lara awọn eeyan wọnyii ti jẹwọ pe awọn n ko nnkan ija oloro wọle si ipinlẹ Ọyọ.

O ni lootọ awọn araalu lẹtọ lati fi ẹhonu wọn han nipa iwọde alaafia, amọṣa awọn kan n lo anfani yii lati kọja aye wọn nipa dida omi alaafia ilu ru.

Awọn ọlọpaa lẹnu iṣẹ nibi iwọde kan

“O ṣe pataki ki n tẹnu mọ ọ pe, a ko ni fi aye gba kikọlu awọn ọlọpaa tabi awọn oṣiṣẹ agbofinro miran.

“Gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lo gbọdọ yago fun awọn arijẹnidimadaru aarin wa ki wọn si tẹsiwaju pẹlu alaafia ti pọ mọ ipinlẹ Ọyọ mọ.”

Ninu ọrọ tirẹ, ọga agba ẹka banki apapọ Naijiria, CBN ni ipinlẹ Ọyọ, Folukẹ Oluduro rọ awọn eeyan ilu lati fọkan balẹ ki wọn ma si ṣe da omi alaafia ilu ru lori inira ayipada owo tuntun.

O ni banki apapọ Naijiria, CBN ti n ṣiṣẹ lori rẹ lati rii pe owo tuntun naa kari.