Owó ni ọkọ mi lọ gbà ní báńkì, kí wọn tó ta á níbọn – Aya ọkùnrin tí ìbọn bà níbi ìwọ́de Abeokuta sọ̀rọ̀

Láti ìgbà tí ọ̀wọ́n gógó owó náírà àti epo bẹntiróòlù ti gbòde kan ní ìwọ́de ti ń wáyé káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.

Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn ènìyàn kan náà kó ara wọn jọ ní ìlú Abeokuta láti ṣe ìwọ́de nítorí ọ̀wọ́n gógó owó náírà àti epo bẹntiróòlù.

Kò pẹ́ ni fídíò kan gba orí ayélujára pé ìjà ńlá ti bẹ́ sílẹ̀ níbi ìwọ́de náà àti pé ọmọkùnrin kan ti fara gba ọta ìbọn.

Fídíò náà ṣàfihàn bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ ṣe ń dà ní ara rẹ̀, tí àwọn ènìyàn sì ń gbìyànjú láti gbe dìde nínú gọ́tà tó fẹ́ ṣubú sí.

Ìdí nìyí tí BBC Yorùbá fi kàn sí ilé àwọn ọmọkùnrin tí ìbọn bà ọ̀hún, láti ṣèwádìí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.

Gabriel Micheal

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Owó ni ọkọ̀ mi fẹ́ lọ gba nílé ìfowópamọ́ kí wọ́n tó pè mí pé ọta ìbọn ti bà á – Ìyàwó Gabriel

Taiwo Micheal, ìyàwó ẹni tó fara gbọta

Nígbà tí a kàn sí ìyàwó rẹ̀, Taiwo Micheal ní òun kò ti ẹ̀ mọ̀ wí pé ọkọ òun ni òun ń wò ní orí ayélujára tí wọ́n sọ wí pé ìbọn bà ní Sapon.

“Lẹ́yìn aṣọ funfun tí mo kàn rí mi mò tó mọ̀ wí pé ọkọ mi ni ìbọn bà nítorí mi ò rí ojú ẹni tó wà nínú fídíò náà.”

Taiwo ní nígbà tó yá ni wọ́n pe òun pé ọkọ òun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí tí òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ní pe gbogbo àwọn tó súnmọ́ ọkọ òun láti tètè dé ibi tó wà.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn náà ló ṣàlàyé fún òun pé ilé ìwòsàn FMC ni wọ́n gbé ọkọ òun lọ fún ìtọ́jú tí òun náà sì lọ báwọn níbẹ̀.

“Ọkọ mi kò ní òbí àti olùrànlọ́wọ́ kankan, ohun tí mo fẹ́ ni bí ara ọkọ mi ṣe ma yá lásìkò”

“Nígbà tí ọkọ mi ń kúrò nílé Ijehun Tuntun ló dágbére fún mi wí pé òun ń lọ àmọ́ ó pè mí nígbà tó yá pé òun máa ya Sapon nítorí òun fẹ́ gba owó ní báǹkì.”

“Kò pẹ́ ni mo ń gbọ́ wí pé wọ́n ń jà ní Sapon, pé wọ́n ń yìbọn, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní pé nọ́mbà rẹ̀ àmọ́ kò lọ, ó ní ó ti kú.”

“Ìgbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ àmọ́ mi ò rí ẹnìkankan pè nínú wọn àmọ́ nígbà tí nọ́mbà rẹ̀ padà lọ ni ẹni tó gbe ló sọ fún mi pé ó ti ṣèṣe pé ìbọn bà á.”

Taiwo ní nǹkan tí òun ń fẹ́ báyìí ni bí ìjọba yóò ṣe ṣàtìlẹyìn fún àwọn tí ara ọkọ òun máa balẹ̀ nítorí nǹkan tó jẹ òun lógún báyìí ni bí ara ọkọ òun ṣe ma tètè yá.

“Ó lọ́mọ nílé, ẹ̀rù ènìyàn méjì kò gbọdọ̀ di ti ẹnìkan lásìkò yìí, kò ní ìyá àti bàbá, èmi nìkan àti àwọn ọmọ la kù fun, a ò ní olùrànlọ́wọ́ kankan.”

Èmi sá wọ agboolé kan nígbà tí a gbúròó ìbọn, mi ò mọ̀ pé Gabriel ló fara gbọta – ọ̀rẹ́ Gabriel tí wọ́n jọ lọ sí báǹkì

Monsuru Kushimo, ọ̀rẹ́ Gabriel Micheal tí wọ́n jọ lọ sí il;e ìfowópamọ́

Monsuru Kushimo tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Gabriel tí wọ́n jọ lọ sí báǹkì nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ ní pé òun àti Micheal Gabriel ni àwọn jọ wà níbi tí àwọn máa ń jókòó sí láti ṣeré tí àwọn sì jọ ń sọ̀rọ̀ pé kò sí owó lọ́wọ́ àwọn.

Ó ní àwọn méjéèjì wá pinnu láti lọ sí Sapon láti lọ gba owó ní First bank nítorí èrò pọ̀ púpọ̀ ní Zenith bank tí òun ń lò.

Monsuru ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn fi máa débẹ̀, àwọn bá àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń dáná sun gbogbo nǹkan àti pé kò pẹ́ púpọ̀ báyìí ni àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn ènìyàn náà.

“Bí èmi ṣe gbọ́ ìró ìbọn ni mo sáré wọ agboolé kan lọ, mo kàn gbọ́ wí pé wọ́n ní wọ́n ti yìbọn fún ẹnìkan ni, kò ṣẹlẹ̀ lójú mi.”

“Mi ò mọ ẹni tó yìbọn, ìgbà tí máa fi jáde kúrò nínú agboolé tí mo sá sí ni mò kàn rí ọ̀kadà tó ti ń gbe e lọ sí ilé ìwòsàn.”

Ọlọ́run ló dá ẹ̀mí Micheal padà, kò mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ mọ́ nígbà tí wọ́n fi máa gbe dé ilé ìwòsàn – Dókítà

Ọ̀gá àgbà ilé ìwòsàn Federal Medical Center, FMC, Dókítà Musa Olomu Adewale tó ṣe ìtọ́jú Gabriel Micheal ṣàlàyé fún wa pé nígbà tí wọ́n gbe dé ẹ̀ka pàjáwìrì lọ́jọ́ náà, kò mọ nǹkan tó ń ṣe mọ́, ó kàn ń jupá ju ẹsẹ̀ lásán ni.

Ó ní gbogbo àwọn nọ́ọ̀sì àti àwọn dókítà ni àwọn ń dì í mú lápá lẹ́sẹ̀, tí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní wá omi àti ẹ̀jẹ̀ láti fi ṣe ìtọ́jú rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ó fi kun pé lọ́wọ́ kàn ni àwọn dókítà tó ṣiṣẹ́ abẹ nípa ẹ̀mí àti iṣan ara bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ abẹ fún-un tí àw’on sì dúpẹ́ pé ara rẹ̀ ti balẹ̀ báyìí.

Ó ní òun ní àrídájú pé ara rẹ̀ máa balẹ̀ dáadáa, tí yóó dìde fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rín láìpẹ́ láì jìnà.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí