Ọmọ-ìkọ́ṣẹ́ ṣékupa ará rẹ lẹ́yìn tí ọkọ ọ̀gá rẹ̀ fipá bá a lòpọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Olayemi Agbelola ,ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo ti sekupa ara rẹ lẹyin ti ọkọ ọga rẹ, ẹni ti a le sapejuwe gẹgẹ bi Ajibode fipa baa lopọ ni ile ti wọn jọ n gbe niluu Eruwa, ni ijọba ibilẹ Ibarapa nipinlẹ Oyo.

Ajibode, ẹni to n se isẹ Welder ni iroyin sọ pe o dunkoko mọ ọmọdebinrin naa pe oun yoo sekupa to ba sọrọ naa fun ẹnikẹni.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch se sọ, Olayemi ni o n kọ isẹ ransọransọ lọwọ iyawo Ajibade, ti o si n gbe pẹlu tọkọtaya naa.

Nnkan yii pada nigba ti ọmọdebinrin naa n sun sinu yara tọkọtaya lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa, ti Ajibade si wọle sinu yara pẹlu ọmọbinrin to si balopọ.

Baba Olayemi ,Sunday Agbelola ni oun gbe ọrọ naa lọ si ileeṣẹ ọlọpaa niluu Eruwa,.

“Olayemi lọ kọ isẹ lọdọ Iyawo Ajibade ni ibẹẹrẹ ọdun yii lẹyin igba ti emi ati iyawo mi pinnu pe o gbọdọ nkọ isẹ ọwọ.

“Ọmọ mi ti n gbe pẹlu Ajibade ati Iyawo rẹ lati ibi oṣu mẹfa, ti wọn sa dede pe wa pe ọmọ mi ti jade laye.

“Ki ọmọ mi to ku, o ni Ajibade lo fipa ba oun lopọ”

Baba Olayemi tẹsiwaju pe ọmọ oun sọrọ ko to da gbere faye ni ile iwosan

“Lẹyin ọ rẹyin ni a gbọ pe Ajibade lo fipa ba ọmọ wa lọ pọ, to si jẹ ki ọmọ wa mu ogun eku.

“Awọn eleto ilera lo fidi ọrọ yii mulẹ lẹyin ti a gbe lọ si ile wosan fun itọju lẹyin to mu ogun eku.

“Ni ile iwosan ni a ti gbọ pe ki ọmọ wa to ku, o ni Ajibade lo fipa ba oun lọpọ to si jẹ pe eyi lo jẹ ki oun gbe ogun jẹ.

“Lẹsẹkẹsẹ ni mo fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti wọn si ti mu Ajibade si ahamọ niluu Eruwa.”

Ọmọ mi ti kọkọ sọ fun mi pe Ajibade maa wọle ti oun ninu yara- Iya Olayemi

Pẹlu omije, Iya Olayemi, Folake Agbelola ni ọmọ oun ti kọkọ pe oun pe Ajibade maa n ni oun lara ti oun ba ti n sun lalẹ.

“N ko le sọrọ bayii nitori wọn ti gba ọmọ mi lọwọ mi. Se isẹ ni pe eeyan lọ kọ isẹ ni

“O sọ fun mi pe ọkọ ọga oun ma ni oun lara ni alẹ ti oun ba ti fẹ sun. M o fẹ ko ma bọ ni ile sugbọn mo tun fẹ ko pari isẹ to lọ kọ.”

Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa, DSP Adewale Osifeso ni iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ, ti awọn yoo si fi to araalu leti ibi ti iwadi naa ba de,

“Ẹsun ifipabanilopọ kan ni wọn fi to wa leti ni agọ ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eruwa.

“Iwadi ti bẹrẹ lori ọrọ naa, a yoo fi abọ wa to araalu leti laipẹ.”