‘Olóyè Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ kánmọ́ kánmọ́ ráńṣẹ́ láti Cotonou nípà owó ìtọ́jú ìlera rẹ̀’

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajugbaja ajafẹtọ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo Igboho ti ni oun ko tọrọ fun owo lọwọ ẹnikẹni lati lo fun ilera rẹ.

Ọrọ yii jade latọwọ ọkan lara awọn agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki to fi soju opo ayelujara pe:

“Iroyin kanmọ kanmọ kan ree lorukọ ajijagbara Sunday Adeyemọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho pe oun ko ran eeyan kankan tabi awọn to n ba oun ṣiṣẹ yala ẹṣọ ni tabi ọrẹ rẹ lati beere owo fun itju ara rẹ ni orilẹede Benin Republic”.

Fidio atẹjiṣẹ yii bọ sita ni ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa ọdun 2021 ninu eyi ti agbẹnusọ rẹ ti n sọ pe lati ọwọ agbẹjọro rẹ kan ni o ti fi ọrọ naa ṣọwọ.

O ni Oloye Sunday Adeyemo Igboho ko beere fun owo lati tọju ara rẹ ni ilu Benin Republic to wa.

Wọn gbọ iroyin pe ọpọ awọn to n ba a ṣiṣẹ to n lo anfani ipo to wa lọwọ lati bere owo fun itọju Igboho, amọ wọ́n ni irọ gbaa ni wọn n pa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Baba wa ti ni ki n sọ fun gbogbo ẹyin ti ẹ jẹ ololufẹ wọn pe ki ẹ ṣọra gidi gan fun awọn ọlọdani tabi to ba n dibọn bii pe oun ran wọn niṣẹ ti wọn si ti n gba owo fun itọju ara oun tori oun ko sọ bẹẹ ko si ran wọn niṣẹ”.

Koiki ni lootọ ni o rẹ Oloye Igboho gẹgẹ bi ẹ ti ṣe n gbọ tẹlẹ amọ ko ran ẹnikẹni lati gba owo fun itọju ara oun.

O fi kun un wipe bi ẹnikẹni ba ri eeyan to n beere owo lọwọ rẹ lorukọ Sunday Igboho ki wọn fi to wọn leti ki wọn lee gbe igbesẹ lori rẹ.