‘Ọ́lọ́run mo dúpẹ́ o pé wọn ò kà mí mọ́ ẹni tó ti wọlẹ̀ báyìí níbi afẹ́fẹ́ gáàsì tó búgbàmù’

Ibi ibugbamu afẹfẹ Gaasi

“Mo wa ninu ibẹ nigba to ṣẹlẹ, o ka mi mọ ibẹ gangan ni, amọ mo dupẹ lọwọ Ọlọrun”.

Ọkan lara awọn ti iroyin yii ṣoju rẹ koda ti ori ko yọ nibi iṣẹlẹ afẹfẹ gaasi to bugbamu lagbegbe Mushin nipinl Eko ba BBC Yoruba sọrọ.

Arakunrin naa ti ko fẹ darukọ rẹ amọ to sọrọ lori fidio BBC Yoruba jẹ ko di mimọ pe ori lo ko oun yọ.

Ibi ibugbamu afẹfẹ Gaasi

“Mi o ki n ṣe ẹni to n ta gaasi, amojuẹrọ lemi, mo fẹ gbe mọto mi jade nibẹ ni, bi mo ṣe fẹ wa mọto sita ni mo gbọ gbamu! Ohun ti mo gbọ niyẹn o”.

Arakunrin naa ni ọkọ oun gan ṣi wa nibẹ to ti bajẹ bayii amọ oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko ka oun mọ awọn to ti wọlẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọlọwọ lowurọ sọ pe eeyan marun ti jẹ Ọlọhun nipe to fi mọ ọmọ kekere ọdọ langba kan to wa lara wọn ni agbegbe Mushin ni Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibugbamu afẹfẹ Gaasi

Awọn olugbe agbegbe naa atawọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ṣaadede lawọn gbọ́ ariwo ibugbamu nla ninu ọja kan to wa lagbegbe naa ni nkan bii ago mẹsan owurọ ọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ti gbe oku awọn to ku kuro nibi iṣẹlẹ yii.

Ileeṣẹ panapana to ti yọju sibẹ sọ fun BBC pe ibugbamu naa ti ṣakoba fun ọpọlọpọ ile to wa lagbegbe rẹ to fi mọ ṣọọbu mọkaliiki kan, ṣọọbu ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ atawọn ṣọọbu afẹfẹ gaasi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn agolo afẹfẹ gaasi

Ajọ to n moju to iṣẹlẹ pajawiri ati oniruuru awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mii lo ti pe sibẹ lati rii daju pe laburu kankan ko ṣẹlẹ.

Ajọ LASEMA sọ pe igbesẹ ati mu ohun gbogbo bọ sipo ti n waye ti wọn si ni apapọ awọn to lee ṣeranwọ idoola ti wa nibẹ.

Nigba ti wọn de ibi iṣẹlẹ naa, wọn rii ibi gbangba lo ti ṣẹlẹ ti wọn n lo fun oniruuru nkan ọrọ aje bii ile ti, ṣọọbu mọkaliiki, ṣọọbu ẹya ara ọkọ ati ṣọ́ọ̀bù afkfẹ́ gaasi.

Ninu atẹjade ti oludari ajọ LASEMA, Arabinrin Margaret Adeseye

Ibi ibugbamu afẹfẹ Gaasi
Gaasi

fọwọ si, iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun to faa gangan awọn yoo si jẹ ki araalu gbọ.

“Nkan bii ago mẹjọ ku iṣẹju diẹ la gba ipe pajawiri naa taa si tete ni ki awọn oṣiṣẹ wa bọ sibẹ.

Lẹyin wakati kan a ri oku eeyan marun un gbe jade – ọkunrin mẹrin ati obinrin kan atipe eeyan mẹwaa la ri to ti farapa”.