Ọlọ́pàá rí òkú ọ̀gá ẹgbẹ́ onímárúwá nílé àkọ́kù, wọ́n gé orí, ìdí àti ọrùn ọwọ́ rẹ̀ lọ

Kẹkẹ Maruwa

Awọn ọkunrin mẹta kan, Abdullahi Ibrahim, Ismaila Ajirẹrin ati Adeọla Adeọṣun ni awọn ọlọpaa ti mu bayii n’Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lori iku ojiji to pa Oloogbe Musibau Aliu, ọga awọn onimaruwa n’Ilọrin.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, DSP Ejire-Adeyẹmi Toun fi ṣọwọ si BBC Yoruba, ṣalaye pe aburo Oloogbe, ti orukọ tiẹ n jẹ Ọlanrewaju Saliman, lo fẹjọ sun lọjọ kẹwaa, oṣu kẹta ọdun 2023 yii.

Teṣan ọlọpaa G Division, Ọlọjẹ, lo mu ẹjọ naa lọ pe ẹgbọn oun gbe kẹkẹ Maruwa rẹ jade ni nnkan bii aago marun-un ọjọ kẹjọ oṣu kẹta yii, lati fi ṣiṣẹ aje.

O ni latigba naa ni ko ti wale mọ, bawọn si ṣe n pe foonu rẹ to, ko gbe e.

Ọwọ́ ba èèyàn mẹ́ta lóri ikú ọ̀gá àwọn onimaruwa – ọlọpaa

Gẹgẹ bi DSP Ejire ṣe wi, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹta ni olobo ta ileeṣẹ ọlọpaa Kwara, pe oku ọkunrin kan wa ninu ile akọku kan loju ọna Okolowo Expressway,lagbegbe Daru-Salam, Ilọrin.

Alukoro naa sọ pe nigba tawọn debẹ pẹlu aburo Oloogbe, ọkunrin naa fidi ẹ mulẹ pe oku ẹgbọn oun, Musibau Aliu ni.

Oku naa ti n jẹra, wọn si ti ge ori, apa kan idi ati ọwọ rẹ mejeeji lọ.

Titi digba ti Oloogbe Musibau lugbadi iku ojiji yii, oun ni Alaga ẹgbẹ awọn onikẹkẹ Maruwa lagbegbe Idiose, Alorin niluu Ilọrin.

Nigba to n ṣalaye nipa awọn afurasi tọwọ ba ọhun, DSP Ejire sọ pe ọmọ agbegbe Medina, n’Ilórin ni Abdullahi Ibrahim.

O ni Agboole Akata, Alorin, n’Ilọrin kan naa ni Ismaila Ajirẹrin ti wa, ẹni ọdun mejidinlogoji ni.(38)

Nigba ti Adeọla Adeọṣun wa lati Agbole Ọmọ, Ẹruda n’Ilọrin, ẹni ogoji ọdun lo pe e.

Iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Wọn lawọn ba ẹbi Oloogbe Musibau Aliu kẹdun, awọn yoo si ri i pe awọn to pa wọn lẹkun jiya to yẹ labẹ ofin.