“Ọlọ́pàá yìnbọn fọ́mọ mí lásìkò ìwọdé EndSars, kò lè rìn, kò le dá yàgbẹ́”

Ridwan Oshodi

Oríṣun àwòrán, Foundation for investigative Journalism

Lẹyin ọdun meji ti iwọde EndSARS waye lorilede Naijiria, oniruuru ipa lo ti ni lori awọn ọdọ, araalu ati awujọ wa lapapọ.

Lara irufẹ ipa buruku kan to tidi iwọde naa jade nilu Eko ni ti ọmọkunrin, ẹni ọgbọn ọdun kan, Ridwan Oshodi to di alaabọ ara.

Nigba to n ba ileesẹ iroyin Punch sọrọ, mama ọkunrin naa to tun jẹ opo, Temitope Oshodi ni ogunjọ  oṣu Kẹwa Ọdun 2020 ni iṣẹlẹ to sọ ọmọ oun di ero ile iwosan bẹrẹ.

O ni lẹyin igbati oun dele lọjọ naa, ni oun gbọ nipa iṣẹlẹ to ṣẹ lagbegbe Lekki sì awọn ọdọ ti o ṣe iwọde EndSars.

“Mo gbiyanju lati ba Ridwan sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ ṣugbọn ko lọ”

Lẹsẹkẹsẹ lo ni oun pe Ridwan ko ma bọ wa si ile, ṣugbọn iṣẹ ti oun se lọwọlọwọ ko fi aaye gba oun lati kuro ni sọọbu nitori iṣẹ aṣọ riran lo n se.

Temitope ni aarọ ọjọ keji lẹyin ti ijọba Eko ti kede iṣede konile-o-gbele ni Ridwan pe oun pe oun wa lọna ile.

Obinrin naa ni ko pẹ lẹyin naa ni oun gbọ iro ibọn lagbegbe afara Ojuelegba nibi ti Ridwan wa.

Temitope ni oun gbiyanju lati ba Ridwan sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ ṣugbọn ko lọ.

“Dokita ni ìbọn ọlọpa gba ikun Ridwan jade, to si ba ọpa ẹyin rẹ jẹ”

Ko pẹ, ko jinna si asiko naa lo ni wọn fi to oun leti pe awọn ọlọpa ti yinbọn fun Ridwan.

Temitope ẹnì ọdun mẹtadinlaadọta fikun pe ile iwosan Havanna to wa ni agbegbe ibiti iṣẹlẹ naa ti waye, ni awọn kọkọ gbe ọmọ oun lọ.

Iya Ridwan ni awọn Dokita ni ìbọn ti awọn ọlọpa yin mọ Ridwan gba ikun rẹ jade, to si ba ọpa ẹyin rẹ jẹ (spinal Cord).

Lati igba naa ni awọn tun gbe lọ si ile iwosan ijọba LUTH, nibiti to ni oun ti na ọpọlọpọ owo lati ri wi pe Ridwan fi ẹsẹ ara rẹ rin.

Abiyamọ naa wa rọ ijọba ipinlẹ Eko lati ran oun lọwọ nitori ibọn ti awọn ọlọpa yin mọ ọmọ rẹ.

Ridwan

Oríṣun àwòrán, Others

“Ridwan ko le fi ẹsẹ ara rẹ rin tabi da yagbẹ funra rẹ, se ni mo n de idi fun bii ọmọde”

Temitope ni lati igba naa nii Ridwan ko ti le fẹsẹ ara rẹ rin nitori gbogbo igba ni oun n de idi (Pampers) fun, ti ko si le da ṣe nkankan.

“Bo tilẹ jẹ wi pe awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Eko pe mi ṣugbọn titi di akọkọ yii, ijọba ko ti i ṣe nkankan lori iṣẹlẹ naa.

Mo wa n rọ awọn alaṣẹ ati awọn ẹlẹyinju aanu lati ran mi lọwọ, kí Ridwan lè fi ẹsẹ rẹ mejeeji rin pada.”

Bẹẹ ba gbagbe, ijọba ipinlẹ ke asẹ konile o gbele lẹyin iṣẹlẹ ipaniyan to waye lẹnu iloro Lekki ni ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020 lasiko iwọde EndSARS.

Isede naa si lo wa ni lati pẹtu si rogbodiyan to waye ni agbegbe Lekki.