Ohun tí a bá bọ̀ níbi ìgbẹ́jọ́ Tani Olohun nílùú Ilorin lónìí rèé

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, BBC/Tani Olohun

Ile ẹjọ kan to kalẹ si ilu Ilọrin ti kede ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan an, ọdun 2023 lati gbọ ẹjọ beeli ti agbẹjọro Tani Ọlọhun pe.

Eyi lo waye nigba ti awọn Musulumi ati awon Onisẹṣe ya bo ile ẹjọ naa fun igbẹjọ gbajugbaja onisẹse ni, Abdulazeez Adegbọla ti apẹle rẹ n jẹ Tani Ọlọhun ati afurasi mii, Oloye Ademọla Ọlawoore, tii ṣe Oluwo nla Tede

Ṣe ni awọn ọlọpaa di oju ona to gba agbegbe ile ẹjọ naa kọja lati rii pe ẹnikẹni ko kọja nigba ti ẹjọ ọhun n lọ lọwọ.

Awon mejeji ni wọn pe lẹjọ fun ẹsun igbimọpọ, itabuku, ibanilorukọjẹ ati dida rogbodiyan silẹ, eyi ti wọn ni o lodi si abala 96, 113, 391, ati 399 ọfin iwa ọdaran Naijiria.

Ti ẹ ko ba gbagbe, wọn ti kọkọ gbe afurasi akọkọ Tani Ọlọhun, wa sile ẹjọ Majisireti kan ṣaaju, lori ẹsun kan naa ti ile ẹjọ si paṣẹ ahamo aadọta ọjọ fun un.

Pẹlu igbẹjọ to waye lonii, oti di ẹẹmeji ọtọọtọ ti won yoo gbe Tani Olọhun wa si ile ẹjọ meji laarin ọjọ mẹfa lori ẹsun kan naa.

Agbẹjọro Abolaji Adisa ti ofi iwe igbẹjọ toni lede lorukọ onibara rẹ, Alfa Okutagi fẹsun kan Tani Ọlọhun ati Oluwo nla Tede pe awọn mejeji tabuku onibara ohun lori ẹrọ ayelujara pe Okutagi jẹ Alfa eke, to si wa agbara lọ si ọdọ awon oniṣẹṣe ni igba aye rẹ.

Wọn tun fẹsun kan awọn afurasi naa pe wọn ni awọn oniṣẹṣe lo ran Okutagidi lọwọ lati gba agbara lọdọ Orisa Osun fun iyawo ọmọ rẹ lati bi ọmọ.

Igbesẹ agbẹjọro tani Olohun lati gba beeli rẹ

Agbẹjọro kan ti ẹgbẹ ti Yoruba Lẹsin gbe dide lati ilu Eko lati ṣoju fun Tani Ọlọhun ati Oluwo nla Tede, Amofin Adedamọla Olalekan ninu ọrọ re fi iwe atako fun ẹjọ ọhun sita fun Ile ẹjọ ọhun.

Agbẹjọro naa ni o tumọ si pe, awọn Alfa to fẹsun kan awọn afurasi naa ko ni ẹtọ labẹ ofin Naijiria lati mu eeyan lọ si ile ẹjọ meji fun ẹsun kan ṣoṣọ.

O ni eleyi jẹ ṣise makaruru eto igbẹjọ.

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, Prince Ademola Ajasa & Co.

Lẹyin naa lo gba ile ẹjọ naa ni iyanju pe ko wọgile ẹjọ ọhun, ki awọn si le gbe ẹjọ naa pada si ile ẹjọ Majisireeti fun igbẹjọ ti akọkọ.

Ṣugbọn agbẹjọro awọn olupẹjọ, Abolaji Adisa bẹ ile ẹjọ fun iyọnda ọjọ meje lati fesi si iwe ipẹjọ agbẹjọro tani Olohun, ṣugbọn agbẹjọro Tani sọ ọjọ meje ti pọ ju lati fesi si ọrọ oun, o si bere pe ki wọn fesi laarin ọjọ kan ṣoṣo.

Ni igbvẹyingbẹyin, adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Sunday Adeniyi sun ẹjọ naa si ọjọ kerin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 fun igbẹjọ sise ẹjọ makaruru ilana eto ofin, ati ọjọ karun un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023, fun igbẹjọ lori beeli Tani Ọlọhun.