“Ọ̀gá ọlọ́pàá ni aya mi, ẹbí mi bií 30 ló jẹ́ ọlọ́pàá, iṣẹ́ tó rẹwà ni, ẹ má tàbùkù rẹ̀”

Awọn osisẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NPF

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejobi ti bu ọla fun iṣẹ ọlọpaa paapaa julọ bi awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan ko ṣe fi oju to dara wo wọn .

 Olumuyiwa lo bu ọla yii fawọn ọlọpaa lasiko to pe akiyesi araalu si fidio kan, nibiti Baba ọmọbinrin kan ti n sọ fun ọmọ rẹ pe ko maṣe ṣe iṣẹ Ọlọpa.

Ninu fọnran aworan naa to wa ni ori ẹrọ ayelujara twitter, Baba naa n rọ ọmọbinrin rẹ lati yan iṣẹ miiran laayo nitori awọn ọlọpa orile-ede yii ko ri itọju to daju.

Ni idahun si fidio naa, Adejobi kilọ fun awọn eniyan lati dẹkun fifun ile-iṣẹ naa ni aworan buburu, paapaa niwaju awọn ọmọde  ti o le dagba lati ni ikorira fun iṣẹ Ọlọpa.

Nigba to n dahun si ibeere kan boya o fẹ ki awọn ọmọ rẹ di ọlọpa,

Adejobi sọ pe awọn ọmọ oun nifẹ iṣẹ naa nitori ọna ti oun fi n wọ aṣọ ọlọpa ati awọn nkan miiran.

O sọ pe inu oun  dun lati jẹ ọlọpa ati pe osisẹ ọlọpa to lè ní ọgbọn lo jẹ ẹbi oun, tawọn si jọ jẹ ibatan.

“Osisẹ ọlọpa ni mi, iyawo mi naa jẹ ọga ọlọpaa, agba ACP ni arakunrin mi, iyawo arakunrin mi si je CSP.

Awon egbon mi si je ọga ninu iṣe ọlọpaa, koda, ninu idile mi a le ni ọgbọn ti a jẹ ọlọpa.

Olumuyiwa Adejobi

Oríṣun àwòrán, AdejobiOlumuyiwa/Facebook