Ọ̀gá àgbà àti òṣìṣẹ́ mẹ́ta nílé ẹ̀kọ́ Chrisland pẹ̀lú òǹtàjà kan fojú balé ẹjọ́ lórí ikú Whitney Adeniran

Aworan Whitney ati ileẹko

Oríṣun àwòrán, instagram

Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ọga agba ile ẹkọ Chrisland to wa ni Opebi nilu Eko ati igbakeji rẹ lọ sile ẹjọ lori iku akẹkọọ kan nile ẹkọ naa, Whitney Adeniran.

Bakan naa ni olukọ meji ati ontaja kan naa kawọ pọnyin nile ẹjọ lori isẹlẹ ọhun ni Ọjọru.

Adajọ Oyindamola Ogala, ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko to wa ni Ikeja, lo n gbọ ẹjọ ẹsun ipaniyan naa.

Awọn osisẹ ilẹ ẹkọ naa ti wọn foju ba ile ẹjọ lọjọru ni Ademoye Adewale, Kuku Fatai, arabinrin Belinda Amao, Nwatu Ugochi Victoria ati ile ẹkọ Chrisland lapapọ.

Awọn osisẹ ile ẹkọ naa ni wọn jẹjọ lori ẹsun meji to nii se pẹlu aimọọmọ lati paniyan, ailakasi ati aikọbi ara si nkan.

Ile ẹjọ gba oniduro awọn afurasi, sun igbẹjọ si Osu karun ati ikẹfa

Whitney Adeniran, to jẹ akẹkọọ ileẹkọ Chrisland ṣaaju iku rẹ, ni awọn osisẹ ile iwe naa bo asiri iku rẹ nitori ọna ti iku rẹ ba de.

Nigba ti wọn gbe wọn wa si iwaju adajọ Ogala, Belinda Amao bu sẹkun bi ileẹjọ ti n gbero lori ọjọ ti igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju.

Gbogbo awọn afurasi to yọju sile ẹjọ naa si lo kede pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Wayi o, ile ẹjọ ti gba oniduro awọn afurasi mẹrẹẹrin naa.

Agbẹjọro agba nipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo sọ fun ile ẹjọ pe ijọba ipinlẹ naa ni awọn lẹri mẹtadinlogun ti yoo ko wa sile ẹjọ ti igbẹjọ naa ba bẹrẹ.

Adajọ Ogala si sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹẹdọgbọn osu Karun ọdun 2023, ọjọ kinni osu kẹfa ati ọjọ kẹjọ sou kẹfa pẹlu ọjọ kẹẹdogun osu kẹfa fun igbẹjọ naa.

Wo awọn ohun to rọ mọ beeli ikọọkan afurasi tile ẹjọ gbe kalẹ:

Awọn olujẹjọ akọkọ – Adewale Ademoye, Candy Flux vendor

Miliọnu mẹwa Naira ni wọn yoo fi gba oniduro awọn mejeji pẹlu oniduro meji to n gbe nipinlẹ Eko.

Awọn oniduro mejeeji naa ni yoo ko iwe irinna silẹ okeere wọn silẹ fun akọwe agba ile ẹjọ naa pẹlu iwe owo ori ti wọn san lati ọdun mẹta sẹyin.

Olujẹjọ keji – Kuku Fatai

Miliọnu mẹwa Naira ni wọn yoo fi gba oniduro rẹ pẹlu oniduro meji to n gbe nipinlẹ Eko, ti owo nla si wa ni apo asunwọn wọn

Awọn oniduro mejeeji naa ni yoo ko iwe irinna silẹ okeere wọn silẹ fun akọwe agba ile ẹjọ naa pẹlu iwe owo ori ti wọn san lati ọdun mẹta sẹyin.

Olujẹjọ kẹta – Belinda Amao

Ogun miliọnu Naira ni wọn yoo fi gba oniduro rẹ pẹlu oniduro meji pẹlu miliọnu mẹwa Naira ẹnikọọkan wọn.

Awọn oniduro mejeeji naa ni yoo ko iwe irinna silẹ okeere wọn silẹ fun akọwe agba ile ẹjọ naa pẹlu iwe owo ori ti wọn san lati ọdun mẹta sẹyin.

Olujẹjọ kẹrin – Nwatu Victoria tii se igbakeji ọga ile ẹkọ Chrisland