Mo fọwọ́ mi gbé ọmọọmọ mi sin nítorí àìṣedédé ètò ìlera Nàìjíríà – Akpabio, ààrẹ ilé aṣòfin Nàìjíríà

Sẹnetọ Akpabio

Oríṣun àwòrán, others

Lorilẹede Naijiria, ọpọ eeyan lo maa n ro wi pe awọn inira ati ijakulẹ ijọba ti mẹkunu n dojukọ kọ kii ṣẹlẹ si awọn olowo ati awọn to di ipo iṣejọba mu.

Amọsa, aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Godswill Akpabio ti sọ wi pe, aisan ti n ṣe ọgọfa naa lo n ṣe ọọdunrun, ohun to ba n ṣe abọyade gbogbo ọlọya lo n ṣe.

Sẹnetọ Akpabio ni lori ijakulẹ eto ilera lorilẹede Naijiria, ohun pẹlu foju wina rẹ nigba ti oun padanu ọmọọmọ oun kan ni ileewosan ijọba lọdun 2019.

‘Ọmọ mi fẹrẹ ya were, ida ọgọta ẹjẹ lo pada ko si si dokita abi nọọsi kankan nitosi lalẹ ọjọ naa’

“Lọdun 2019, ọmọ ọmọ mi akọkọ da ẹjẹ lara ku ni ni ile iwosan ijọba apapọ kan.”

Eyi lọrọ ti Aarẹ ile aṣofin apapọ sọ leti igbọ awọn akẹgbẹ rẹ lasiko ti wọn fi n ṣe ayẹwo fun awọn ti o fẹ di minisita labẹ ijọba Aarẹ Bla Tinubu.

Sẹnetọ Akpabio ni nṣe ni ọmọọmọ oun naa n gba omi lo ba gbodi laarin oru laisi oṣiṣẹ ilera kankan nibẹ to lee ran an lọwọ.

“O n wa omi lati mu. O yi titi lori ilẹ ile iwosan naa bọ sita ninu iri owurọ to n sẹ. Ko si dokita bẹẹni ko si nọọsi kankan lati ran an lọwọ. O da ẹjẹ lara ni titi ti o fi padanu ida ọgọta ninu ọgọrun ẹjẹ to wa lara rẹ.”

Sẹnetọ Akpabio ni ọmọ oun naa fẹrẹ ya were. O yi titi pẹlu irora ki o to jabọ sori ilẹ.

Seneto Akpabio

Oríṣun àwòrán, nass

Akpabio to ti figbakanri jẹ gominia ipinlẹ Akwa Ibom ṣalaye siwaju sii pe nigba to ya, ọmọ naa daku lọ gbọrangandan ni.

Aarẹ ile aṣofin naa sọ nigba ti ile n se ayẹwo fun Tunji Alausa to jẹ ọkan lara awọn ti Aarẹ Tinubu fi orukọ wọn ranṣẹ fun ayẹwo si ipo minisita pe ko si obi naa lorilẹede Naijiria to yẹ ko tu la iru irora yii kọja.

“Ọwọ ara mi bayii ni mo fi jijakadi irapada ọmọ mi boya yoo le pada ji, ṣugbọn pabo lo ja si. Mo di pa oju rẹ de, mo si gbe oku rẹ si ile igbokupamọsi lọjọ naa.”