Mo ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olùdásílẹ̀ Boko Haram, wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ fún mi – Obasanjo

Olusegun obasanjọ, Aarẹ tẹlẹ lorilẹede NAijiria.

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ṣalaye pe aisi iṣẹ ati iṣẹ lo mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn Boko Haram bẹrẹ iṣẹ laabi wọn.

Oluṣẹgun Ọbanjọ sọ wi pe nibi ipade ti oun kọkọ ṣe pẹlu awọn oludasilẹ ẹgbẹ agbebọn Boko Haram ni igba to kọkọ bẹrẹ paa ni awn oludasilẹ ẹgbẹ alakatakiti naa ti sọ pe ko si ohun meji to sun awọn de idi rẹ ju iṣẹ ati airiṣẹ lọ.

Ọbasanjọ ṣalaye lori eyi lasiko to fi n dahun ibeere nibi eto ifilọlẹ iwe kan ti ọmọ rẹ obinrin, Dokita Kofo Ọbasanjọ-Blackshire kọ.

“Ni ibẹrẹ pẹpẹ idasilẹ ẹgbẹ agbebọn Boko Haram, nigba ti wọn ni wọn pa ọkunrin gan to da a silẹ, mo ni mo fẹ ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati mọ ohun ti wọn fẹ gan an.

“awọn aṣoju wọn ti mo ba pade sọ pe ko si nnkan ti awọn fẹ ju igbe aye to dara sii. N jẹ a wa le da wọn lẹbi fun bibeere fun igbe aye to dara bi?”

Akoso ẹya gbogbo ṣe pataki fun ikẹsẹjari ijọba tiwantiwa – Ọbasanjọ

Aarẹ tẹlẹ naa fi kun un pe awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram nigba naa sọ pe pupọ awọn lo jade ile ẹkọ, ṣugbọn ti awọn ko ri iṣẹ fi ṣe.

O ni lasiko ti oun fi jẹ olori ijọba ologun lorilẹede Naijiria, oun ṣe ipade kan pẹlu awọn alaṣẹ banki agbaye, eleyi to fihan pe awọn alaṣẹ ilẹ okeere mọ awọn aleebu wa, bi wọn ba si ti mọ aleebu eeyan oun gan ni wọn maa n lo lati gba wọle si irufẹ orilẹede bẹẹ lara.

Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ fi kun un pe ki iṣejọba tiwantiwa to lee kẹsẹjari lorilẹede Naijiria, orilẹede Naijiria gbọdọ kọ bi a ṣe n ṣe akoso awọn iyapa ẹsin ati ẹya rẹ gbogbo.