Mi ò ní sin òkú ọmọ mi títí màá fi rí ìdájọ́ òdodo gbà, kò báà jẹ́ ọgbọ̀n ọdún – Baba Sylvester Oromono

Sylvester Oromoni ati awọn obi rẹ

Oríṣun àwòrán, others

Baba Sylvester Oromoni ,akẹkọọ Dowen College to ku laipẹ yii sọ pe oun ko ni i sin oku ọmọ naa titi idajọ ododo yoo fi waye lori iku rẹ.

Ọgbẹni Oromoni sọrọ naa lẹyin ti Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu kede pe iku lati ọdọ Ọlọrun lo pa ọmọ naa.

Ọgbẹni Odumosu sọ pe ayẹwo ti wọn ṣe si oku ọmọdekunrin naa fihan pe kii sẹ ẹnikẹni lo fa iku rẹ, gẹgẹ bi iroyin ṣe n sọ .

Ṣugbọn nigba to ba iwe iroyin Punch sọrọ, Ọgbẹni Oromoni sọ pe idile oun ti pinnu pe dandan ni ki awọn ri idajọ gba lori iku ọmọ wọn.

O ni oun ko ni i sin oku ọmọ naa titi idajọ yoo fi waye, koda ko sẹ ọgbọn ọdun.

“Idile mi ko ni agbara. Ọlọrun ni a gbojule. Ṣugbọn, ti Ọlọrun ba da ẹmi mi si fun ogun ọdun tabi ọgbọn ọdun, mi o ni jawọ ninu ẹjọ yii.

“Ẹru ko ba mi, nitori mo mọ pe ijọba kan ko le wa nibẹ lailai. Ẹmi ọmọ naa n ké kaakiri. Ọlrun wa laaye, ko si si ẹni to le fun ni abẹtẹlẹ.”

O ṣalaye pe oun mọ pe magomago wa ninu esi ayẹwo oku ti ijọba ipinlẹ Eko kede.

Ikú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló pa Sylvester Oromoni – Ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ko si ẹri to daju lati fidi rẹ mulẹ pe awọn kan lo lu akẹkọọ ile ẹkọ Dowen ni Lekki, Sylvester Oroomoni ki ẹmi to bọ lẹnu rẹ.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ṣalaye fawọn akọroyin lọjọ Ẹti pe ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ pe wọn fipa fun Sylvester ni kẹmika mu ki o to ku.

Odumosu ni esi ayẹwo oku ti wọn ṣe lara oku Sylvester fihan pe iku ati ọdọ Ọlọrun wa ni akẹkọọ ọmọ ọdun mejila naa ku.

Ọga ọlọpaa naa tun sọ pe ko si ẹri bakan naa lati fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹgbẹ Sylvester kan fẹ fi ipa mu wọ ẹgbẹ okunkun bakan naa.

Ọgbọnjọ oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Sylvester ku lọna to ya ọpọ eeyan lẹnu.

Ileeṣẹ ọlọpaa mu akẹkọọ marun un ati olukọ mẹta ti Sylvester darukọ wọn ki ẹmi to bọ bọ lara rẹ.

Amọ, wọn ti gba beeli gbogbo wọn lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe wọn mọ nipa iku Sylvester.

Ẹwẹ, baba Sylvester ti sọ pe ohun ti idile oun n fẹ ni ki ile ẹkọ Dowen ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni ọmọ oun.

Àwọn ọ̀dọ́ Ijaw ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn pé ìdájọ́ ikú Sylvester Oromoni kò tẹ́ wọn lọ́rùn

Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ijaw ní Ọjọ́bọ̀ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn ní iwájú ilé ẹ̀kọ́ Dowen College, Lekki.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ṣe wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni.

Bákan náà ni wọ́n ń sọ wí pé ilé ẹ̀kọ́ Dowen College kò tí ì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ewẹ̀, bàbá Sylvester Oromoni ti rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó láti fi èsì àyẹ̀wò ikú ọmọ òun léde fún gbogbo aráyé.

aworan ileewe Dowen ati aworan Sylvester

Oríṣun àwòrán, Rapid response/facebook/other

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College mọ́

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College kò lọ́wọ́ nínú ikú olóògbé Sylvester Oromoni.

Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n ti fẹ̀sùn kàn ṣaájú wí pé wọ́n lọ́wọ́ nínú okùnfà ikú ọmọ ọdún méjìlá náà ni wọ́n ní wọn kò ní ẹjọ́ kankan láti jẹ́ mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Adétutù Oshinusi tó jẹ́ Adarí ẹ̀ka abániṣẹjọ́ ìpínlẹ̀ Èkó (DPP) ló gba Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lámọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí àyẹ̀wò ilé ìwòsàn ti ní kìí ṣe kẹ́míkà ló pa á.

Nínú àkọráńṣẹ́ kan tí wọ́n fi ṣowọ́ sí igbákejì kọ́míṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, SCID àti májísíréètì tó wà nídìí ẹjọ́ náà ni Oshinusi ti gba ìjọba lámọ̀ràn bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ni ìjọba ní kò sí ẹ̀rí kankan láti fi fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn kankan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni Favour Benjamin (16), Micheal Kashamu (15), Edward Begue (16), Ansel Temile (14) ati Kenneth Inyang (15).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Orúkọ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní wọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà àìbìkíkà tí wọ́n fi kàn wọ́n ni Celina Uduak, Valentine Igboekweze, Hammed Ayomo Bariyu, Adesanya Olusesan Olusegun ati Adeyemi.

Ìjọba wá pa á láṣẹ wí pé tí ọ̀kan nínú àwọn afurasí yìí bá ṣì wà ní àhámọ́ ni kí wọ́n tú sílẹ̀ lẹ́yẹ ò sọkà.

Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á – Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko

Baba Sylvester Oromoni, akẹkọọ ile ẹkọ Dowen College nilu Eko ti iroyin sọ pe awọn akẹẹgbẹ rẹ pa ti sọ pe ayẹwo oku ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta fọwọ si ni oun fọwọ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021 ni esi ayẹwo naa jade.

Ninu ayẹwo naa ni onimọ nipa ẹya ara, Dokita Clement Vhriterhire ti sọ pe ọgbẹ ti kẹmika oloro fa ninu ẹdọforo ọmọ naa lo pa a.

Awọn nkan miran to tun mẹnu ba ni pe:

  • Oke ètè rẹ bó
  • Egbo wa ni ẹyin rẹ
  • Ikun rẹ wu
  • ọgbẹ wa ninu ẹdọforo rẹ
  • Ẹdọ rẹ wu

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si

Baba Sylvester, ọgbẹni Oromoni sọ ọrọ yii lẹyin ti iroyin sọ pe kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ní esi ayẹwo ti wọn ṣe si oku ọmọ naa nipinlẹ Eko, ko tọka si pe ẹnikẹni lo ṣokunfa iku rẹ.

Ọgbẹni Odumosu sọ pe awọn obi oloogbe, awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn fi ẹsun iku rẹ kan, awọn alaṣẹ ile ẹkọ Dowen, ati aṣoju ijọba lo wa nibi ti awọn ti ṣe ayẹwo nipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa lo sọ pe awọn gba beeli awọn olukọ ile ẹkọ naa ati awọn akẹkọọ to jẹ afurasi, nitori pe ko si nkankan to tọka si pe awọn lo pa Sylvester Oromoni.

Ati pe wọn ti lo ju ogunjọ lọ ni ahamọ, eyi to tako ẹtọ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni gbigba beeli wọn ko tumọ si pe ẹjọ ti pari lori ọrọ iku ọmọ naa.

O ni esi ayẹwo miran ti wọn fi n mọ boya nkan oloro wa ninu ara lo ku ti awọn n reti bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ni Sylvester kú, ti awọn obi rẹ si sọ pe awọn akẹkọọ kan lo lu u nitori o kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.

Ṣugbọn awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa sọ pe ori papa bọọlu ni Sylvester ti farapa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ