Mercy Aigbe kéde orúkọ tuntun lẹ̀yìn ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Adekaz

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, realmercyaigbe

Oniruuru ẹnu lo ti n kun gbajugbaja oṣerebinrin, Mercy Aigbe bayii lori ayelujara nitori bo se sọrọ soke nipa orukọ rẹ tuntun to n jẹ bayii.

Eyii lo waye lẹyin to ṣafihan ọkọ rẹ tuntun, Kazim Adeoti, ti ọpọ eeyan mọ si Adekaz Production.

Mercy, to ti maa n pe ara rẹ ni aya The Owner tẹlẹ, lo ti kọkọ ṣafihan okunrin naa fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ, iyẹn lẹyin ti awọn kan ti kọkọ n gbe iroyin kiri pe ere ifẹ wa laarin oun ati ọkunrin naa.

Amọ nigba to ku ọjọ kan ki ọkunirn naa ṣe ọjọ ibi, lo kii ku oriire ọdun tuntun loju opo Instagram rẹ, to si n ki ni mẹsan an mẹwaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Se Mercy Aigbe ti lọ si Mecca ni, lo se pe ara rẹ ni Alhaja?

Ninu atẹjade kan to fi soju opo Instagram rẹ lọjọ Aje ni Mercy ti pe Adekaz ni Ọba lori aye rẹ.

O ni “Alhaji ati Hajia Kazim Adeoti”

“Mo ṣi n ṣe ajọyọ ọjọ ibi Ọba mi lọwọ!”

“Adura mi ni pe ohun ayọ ni a oo maa ba ọ ṣe titi ọjọ aye rẹ.”

Mercy tẹsiwaju ninu adura naa pe “Mo dupẹ lọwọ rẹ pe o jẹ alaafia fun mi, mo gbadura ki Ọlọrun tubọ maa bukun fun ọ, ko si tun gbe ọ ga ju iwoye rẹ lọ.”

Ọpọ ololufẹ Mercy lori ayelujara lo wa n beere pe se oserebinrin naa ti lọ si Mecca ni, lo se pe ara rẹ ni Alhaja Adeoti?

Ti ẹ ko ba gbagbe, Mercy ti kọkọ fidio ka sita loju Isntagram rẹ, nibi ti olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal ti n kii, to si n pe aya “the owner.”

Ta ni Kazim Adeoti, Adekaz?

Alhaji Adeoti Kazim ni orukọ ọkọ Mercy tuntun yii amọ orukọ ti ọpọ eeyan mọ ọ si ni Adekaz.

Adekaz yii ni orukọ ileeṣẹ rẹ to n gbe sinima jade, iyẹn Adekaz Production.

Yatọ si eyii, okunrin naa tun ni oludasilẹ ileeṣẹ Ibaka TV, to jẹ ẹrọ ori ayelujara ti awọn eeyan ti n sanwo lati wo sinima.

Ọmọ bibi ilu Orokun nipinlẹ Kwara ni Ọgbẹni Adekaz, amọ ilu Eko ni wọn fi ori rẹ sọlẹ si.

Fasiti ilu Jos lo ti kawe gboye nipa imọ amojuto okoowo.

Ọdun 2002 lo fẹ iyawo rẹ akọkọ, ko to fẹ Mercy Aigbe bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ