Máṣe sọ tíì eléwé àti kọfí rẹ nù, ó lè sọ ọ́ di olówó

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yoruba ni ori lo mọ isẹ asela, ki sba oke ma jẹ ka daamu, ka to ja ọna.

Ọdọmọbinrin kan ree, Adedamọla Adebukọla, ti ko ni oluranlọwọ lẹyin eto ẹkọ girama, amọ ti ko setan lati gbe igba nabi abi tọrọ agbe, sugbọn to wa ohun ti yoo se jẹun dọjọ alẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kini Adebukola tun sọ nipa sise amulo kọfi fun isẹ́ ọnà?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Adebukọla ni osu marun pere ni oun fi kọ isẹ aworan yiya, eroja ohun mimu kọfi, Zobo ati tii elewe Lipton si ni oun fi maa n ya aworan.

O ni owo ti wọn fi n ra ọda lati fi ya aworan ti kọja agbara oun, ni oun se yan lati maa lo awọn eroja naa, ti owo wọn ko gunpa rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ayaworan kọfii naa ni isẹ kekere owo nla ni fifi kọfi ya aworan jẹ nitori owo nla lo n mu wa fun oun.