Lẹ́yìn Titi Masha, Kwam 1 gbé ìyàwó tuntun, Emmanuella Ropo l’Abeokuta, bó ṣe lọ rèé

Kwam 1 ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, PM News Nigeria

Lẹyin ọdun mẹta ti gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si Kwam 1 fẹ iyawo rẹ kekere, Titi Masha ni Ijebu-Ode, agogo igbeyawo tun ti dun laarin olorin naa ati ọmọ ẹlẹ kan, Emmanuella Ropo.

Lọjọru ọsẹ ni igbeyawo Kwam 1 waye niluu Abeokuta pẹlu apọnbeporẹ arẹwa obinrin, Aderopo Emmanuella ti gbogbo ilu mi titi.

Ropo jẹ ẹni to ti le ni Ogoji ọdun lọjọ ori nigba ti Wasiu Ayinde jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta to si ti ni ọmọ to le ni ogoji latọdọ ọpọlọpọ obinrin.

Amọṣa kii ṣe pe o fẹ gbogbo wọn sile.

Iyawo ti wọn mọ mọ Kwam 1 ju ni Yewande to n gbe ni Canada ti wọn si ni ọmọ marun papọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Emmanuella Ropo àti Kwam 1

Oríṣun àwòrán, Kwam1

Wasiu ko fi bo rara gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ ni alaya pupọ eyi ti oloyinbo n pe ni Polygamist to si ni oun ko tii de ipo ti Fela Anikulapo gbajugbaja olorin to ti d’oloogbe to ni akọsilẹ iyawo mẹtadinlọgbọn.

Oṣu to kọja ni iroyin brẹ si ni ta si awọn eeyan leti pe Kwam 1 tun ti fẹ ṣe iyawo pẹlu ẹlẹ tuntun yii. Koda o fi orin kan sori ayelujara ninu eyi to ti n pe e ni “Ajike Okin ati Neulla Ajike Mi”.

Emmanuella naa fi ọrọ ifẹ rẹ sita nipa igbeyawo naa to n gbadura fun ẹmi gigun ninu ifẹ ati idunu fun oun ati Kwam 1.

Emmanuella Ropo àti Kwam 1

Oríṣun àwòrán, EmMANUELLA Ropo/Instagram

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ