Kudirat Odukanmi, Iyabo Oko jáde láyé

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja oṣere tiata, Kudirat Odukanmi ti ọpọ mọ si Iyabo Oko ni o ti jade laye lowurọ oni.

Ọmọ oṣere naa, Aishat Adebisi lo fi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC News Yoruba pe iya oun ti dagbere fun aye.

Lọdun 2022 ni iroyin kan jade pe oṣere naa ti jade laye sugbọn lẹyinọrẹyin ni a gbọ pe iya ọhun ko ku, o si wa laye.

Iyabo Oko, ẹni ọgọta ọdun ni kudiẹkdiẹ ti de ba ilera ara lati ọdun 2015, ko to wa jade laye loni

Aisan yii ni ko fun Iyabo Oko laye lati le kopa ninu ere sinima gẹgẹ bi ti tẹlẹ.

Wọn bi Iyabo Oko ni ọjọ kẹdogun oṣu kọkanla, ọdun 1960 niluu Iwo nipinlẹ Osun.

O darapọ ẹgbẹ ere sinima Ede Onileola lọdun 1973