Kò tíì pẹ́ jù bí ìjọba bá leè sọ ẹni tó pa olóògbé Bola Ige- Gani Adams

Oloye Bola Ige

Gbogbo igba ti awọn ọmọ Yoruba ba ranti igba aye ati ẹyin oloogbe Oloye Bola Ige to tun figba kan jẹ adajọ agaba orile-ede yii tẹlẹ ri, wọn kii tete mẹnu kuro lori ipa pataki to ko ni Naijiria lapapọ.

Oni tii ṣe ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila lo pe ọdun mejidinlogun ti molumọọka oloṣelu yii jade laye.

Ṣugbọn ọpọ eeyan ṣi gbagbọ pe wọn pa a ni ti ko si tii si ẹnikẹni to jẹwọ ẹni to pa a titi di oni.

Lara awọn agbaagba Yoruba, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams sọ iru eeyan ti Bola Ige jẹ ati ẹdun ọkan rẹ nipa iku to pa a lai foju han.

O mu u wa si iranti pe ọkan ninu awn agba oṣelu ti itan rẹ ko le parẹ ni ilẹ Yoruba ni oloogbe Bola Ige jẹ, o dẹ ọkan ninu awọn eeyan ti Ọlọrun fun ni ẹbun agbekalẹ̀ ọ̀rọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“O jẹ ẹni to nigbagbọ ninu iran Yoruba ati ilẹ Naijiria o si wa ninu awọn opo to gbe Naijiria ro lasiko ijọba ologun”.

Aarẹ Gani Adams sọ wi pe fun oun, o jẹ ọkan lara awọn agba ti oun ri bii ṣin iwaju ti awọn tọ ipasẹ rẹ de ibi ti wọn de lonii gẹgẹ bi adari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ, nipa iku oloogbe Bola Ige, Iba Gani Adams ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe ẹni to wa lara awọn to wa ni ijọba gẹgẹ bi agbẹjọro agba fun Naijiria ti wọn si deede wọle pa a bii adiyẹ.

O ni lati igba ti wọn si ti pa a, ko sni to mọ ẹni to pa a titi di oni.

“Iku oloogbe Bola Ige ṣi alafo kan silẹ ti ko si oloṣelu kankan to lee di titi di asiko yii”.

Adams ranti pe inagijẹ ti wọn maa n pe oloogbe Ige nigba naa ni “Cicero of Esa Oke” tori pe ko si ohun gbogbo to ṣẹlẹ lati igba ti wọn ti bi i ti ko ranti”.

Ṣe ẹjẹ rẹ ko ṣi maa ke tantan bayii?

Ṣe o wa yẹ ka gbagbe pe a ko ṣi mọ ẹni to pa a ni ibeere ti akọroyin beere lọwọ Iba.

Iba Gani Adams ti ẹnu bọ ọrọ pe bi ijọba ko ba ti jẹ ki wọn mọ ni to pa irawọ nla ni inu orilẹ-ede, Ọlọrun kii yọnu si iru orilẹ-ede bẹ́ẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ranti awọ́n eeyan nla mii bii MKO Abiola, Layi Balogun, Suliat Adedeji ati bẹẹ bẹ lọ to ku iku oro ti ijọba ko dajọ ododo fun awọn to lọwọ ninu iku wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Tẹ ba wo oloye Bola Ige, irawọ nla ni, ogo nla ni, ẹlẹjẹ funfun dẹ ni, ti èèyàn bá ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, kò sí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ yọnu sí irú orílẹ̀èdè bẹ́ẹ̀”.

Aarẹ Ọna Kakanfo ni iku oloogbe Bola Ige gẹgẹ bi eeyan nla ni ko jẹ ki awọn ọmọ ologo to wa loke okun atawn oludokoowo wale.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ