Kíni àjọ ECOWAS ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń sọ báyìí lórí ìjà Russia àti Ukraine?

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ogun tó ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine tún ń le si bó ṣe ti wọ ọjọ́ kẹfà tí Russia ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine lónìí.

Russia kò sinmi láti máa kó àwọn ọmọ ogun àti àwọn ohun ìjà ogun súnmọ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè Ukraine, Kyiv.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini ECOWAS ile Adulawo n so?

Bákan náà ni àjọ ECOWAS nínú àtẹ̀jáde kan ní aáwọ̀ tó ń wwáyé láàárín àwọn ìlú ti ń mú ẹ̀mí púpọ̀ lọ jù.

Àjọ ECOWAS rọ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti sọ ọ̀rs ní tùbí ń nùbí, kí wọ́n sinmi ogun.

Àwọn orílẹ̀-èdè ECOWAS ni Benin, Burkina Faso, Cabo Verde, Cote D’ivoire, Gambia, Ghana, Guinea, Guinea Bissau, Liberia, Mali, Niger, Nigeria, Senegal, Sierra Leone àti Togo.

Orílẹ̀ èdè Ghana ni orílẹ̀ èdè ECOWAS àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ kéde àtìlẹyìn fún Ukraine.

Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè EU náà kò gbẹ́yìn nínú àwọn tó ń ṣe ti Ukraine.

Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé Ukraine ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ara ìlú ló pàdánù ẹ̀mí wọn níbi àdó olóró tí Russia jù sí ìlú tó tóbi ṣìkejì ní Ukraine lẹ́yìn Kyiv, ìyẹn Kharkiv.

Láti ìgbà tí Russia ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine lọ́jọ́bọ̀ tó kọjá ni àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé ti pín lórí ta ni wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún nínú ìkọlù náà.

Bí àwọn kan ṣe ń faramọ́ ìkọlù tí Russia ń ṣe sí Ukraine ni àwọn kan ń bú ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Vladimir Putin fún ìgbésẹ̀ tó gbé yìí.

Àwọn orílẹ̀ èdè wo ló ń ṣàtìlẹyìn fún Ukraine?

Gbogbo àwọn orílẹ̀ ọgbọ̀n tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ NATO níbi tí àwọn alágbára ayé bí i US, UK, France àti Canada wà ló ti fi àtìlẹyìn wọn hàn fún Ukraine.

Lára ohun tí Putin ṣe ń kógun ja Ukraine ni pé ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ NATO.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Joe Biden wà lára àwọn olórí orílẹ̀ èdè NATO tó kọ́kọ́ dìde láti bu ẹnu àtẹ́ lú Russia nígbà tí ìkọlù náà bẹ̀rẹ̀.

Ojú tí Amẹ́ríkà fi wo ọ̀rọ̀ yìí náà ni gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè abẹ́ G7 fi wo ìkọlù náà.

Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè G7 bíi Canada, France, Germany, Italy, Japan àti United Kingdom náà ti kọrin àtìlẹyìn fún Ukraine.

Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtìlẹyìn fún Russia àti àwọn tó wà lẹ́yìn Ukraine

Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ Ukraine Volodymyr Zelensky ní ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yìí fi ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn orílẹ̀ èdè wo ló ń ṣàtìlẹyìn fún Russia?

Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tó wà lábẹ́ àjọ Collective Security Treaty Organization (CSTO), ẹgbẹ́ kan tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn tí Soviet Union túká jẹ́ àwọn tó ń ṣàtìlẹyìn ọmọ ogun fún Russia.

Lára àwọn orílẹ̀ èdè abẹ́ rẹ̀ Armenia, Belarus, Kazakhstan, Kyrgyzstan àti Tajikistan.

Ukraine ti fẹ̀sùn Belarus pé ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kún ikọ̀ Russia ṣùgbọ́n Ààrẹ Belaru, Alexander Lukashenko ní kò rí bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ni Russia tún rí àtìlẹyìn láti àwọn orílẹ̀ èdè bíi Cuba, Nicaragua àti Venezuela.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awon wo ni ko si leyin enikankan?

Orílẹ̀ èdè China àti Iran dúró ní dáńfó

Kókó ibi tí orílẹ̀ èdè China dúró lé kò yé ni.

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè China Wang Wenbin sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò fara mọ́ ogun àwọn gbà pé Ukraine náà ni ẹ̀bi tirẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀.

Bákan náà ló ní ìbẹ̀rù Russia lórí ètò ààbò rẹ̀ yé àwọn.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ọmọ ṣe ṣorí ní Iran bí Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè rẹ̀ Hossein Amir Abdollahi ṣe di gbogbo ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà NATO.