Kíndìnrín àti ẹ̀dọ̀fóró Sunday Igboho ni àìsàn ń ṣe – Yomi Aliyu

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram

Agbẹjọro Oloye Sunday Igboho, Yomi Aliyu, SAN, ti sọ pe aisan to n ba ajijagbara naa finra kii ṣe keremi, o si nilo itọju kanmọ n kia ati adura gidi.

Aliyu lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lọjọ Isẹgun.

O ni aisan to n ba Igboho finra kii ṣe eyii to n ṣe e tẹlẹ, ṣugbọn aisan naa bẹrẹ lẹyin ti ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣakọlu sile rẹ niluu Ibadan lọjọ kinni, oṣu Keje ọdun yii.

Aliyu ni “Aisan ti ko ṣe igboho tẹlẹ lo bẹrẹ si n ṣe nibẹ, aisan naa le to bẹẹ ti wọn fi gbe digbadigba lọ sile iwosan.”

“Mi o le sọ ni pato boya wọn ti da pada sinu ọgba ẹwọn to wa tẹlẹ lati ile iwosan, ṣugbọn ohun ti mo mọ nipe ara rẹ ko ya, o si jọ bii pe aisan naa ti n daamu kindinri ati ẹdọforo rẹ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Bo tilẹ jẹ pe mi o le sọ nipa ibi gan ti aisan naa ti n ba finra julọ, ṣugbọn mo mọ pe o kan awọn ẹya inu rẹ.”

Aliyu ni aisan ọhun bẹrẹ lasiko to farapa nibi to ti n gbiyanju lati ṣa asala lọwọ awọn ọtẹlẹmutyẹ DSS to kọlu ile rẹ ni ibẹrẹ oṣu Keje.

O ni idi ree ti wọn fi gbọdọ gbe ajijagbara ọhun lọ si oke okun fun itọju to peye.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni ikọ ọtẹmuyẹ DSS ti kọkọ kọlu ile rẹ nilu Ibadan, nibi ti wọn ti ba ọpọlọ dukia jẹ, ti wọn si tun pa eeyan meji nibẹ.

Irọ ni, Sunday Igboho ko si nile iwosan – Amofin Salami

Ẹwẹ, agbẹjọro Sunday Igboho to n fi ilu Cotonou ṣebugbe, Amofin Ibrahim Salami sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si Salami lati mọ ile iwosan ti wọn gbe Sunday Igboho lọ nilu Cotonou, o ni ko si aisan kankan to n ṣe Igboho ati pe ko si nile iwosan.

Salami ni “Sunday Igboho ko ṣaisan, ṣugbọn o ni awọn ipalara kan nitori ikọlu ti ajọ DSS ṣe sile rẹ lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021.”

“Lati igba naa wa, ko ri iwosan to peye gba, ilera rẹ si n buru si, idi ree to fi beere pe ki wọn gbe ohun lọ soke okun fun itọju.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ