Kí ìbò tó dé ni èmi àti Makinde ti ń sọ̀rọ̀, kò sí ìjà mọ́ láàrín wa – Olopoeyan

Aworan Olopoeyan ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan pataki ninu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ‘New Nigeria People’s Party (NNPP)’ n’ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abulrasheed Adebisi Olopoeyan ti ṣe alaye wi pe abẹwo ti oun ṣe si Gomina to wọle fun saa ikeji n’ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ko tumọ si wi pe oun fẹ pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Agba ẹgbẹ ni Ọlọpọeyan jẹ tẹlẹri ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) n’ipinlẹ Ọyọ, ki o to di pe ede aiyede waye laarin oun ati Gomina Makinde lẹyin ti o wọle fun saa akọkọ.

Aigbọraẹniye yii lo si mu ki Ọlọpọeyan fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ti o si lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NNPP saaju eto idibo ọdun 2023.

Nnkan iyalẹnu to ṣẹlẹ ni bi aworan Ọlọpoeyan ati Makinde ṣe lu sita lori ayelujara lẹyin ọjọ diẹ ti Makinde wọle fun saa ikeji ninu eto idibo si ipo Gomina ti o waye n’ipinlẹ Ọyọ.

BBC Yoruba ṣe abẹwo si Ọlọpọeyan fun ifọrọwerọ lori aworan yii ati ede aiyede to waye laarin oun ati Makinde.

Alaye to ṣe fun akọroyin wa ni pe lootọ ni ija wa tẹlẹ laarin oun ati Gomina ipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn ija naa pari saaju eto idibo ọdun 2023.

“Emi ati Gomina Ṣeyi Makinde ti wa tipẹ”

Ọlọpọeyan ni, “Emi ati Gomina Ṣeyi Makinde ti wa tipẹ. Bi ija ba wa de, ti eeyan ba si pari ija, eeyan pari ẹ naa ni.

Kii dẹ ṣe ija naa lo fi bẹẹ de laarin wa. Emi funra mi ni mo sun sẹyin. Kii ṣe ija rara, a dẹ ti jọ wa pọ pada.

Ko ti ẹ to nnkan to yẹ ki awọn oniroyin maa wa mi kiri fun, nitori to ba jẹ ẹni ti a ko jọ ni ajọṣepọ tẹlẹ ni, ẹ le maa bi mi pe kini mo n wa nibẹ”.

O ni ki ibo to de ni oun ati Makinde ti jọ n sọrọ, ṣugbọn aworan ti awọn jọ ya ni aipẹ yii lo mu ki ariwo sọ.

Lori iroyin mii to tun ja ranyinranyin kaakiri pe o ṣeeṣe ki Ọlọpọeyan darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, alaye ti oloṣelu naa ṣe fun wa ni pe ko si nnkan ti oun fẹ lo ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ọlọpọeyan ni inu ẹgbẹ oṣelu NNPP ni oun wa lọwọlọwọ bayii.

A beere nipa awọn ẹsun ti Ọlọpọeyan fi kan alakoso lilọ-bibọ ọkọ ero n’ipinlẹ Ọyọ, Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si ‘Auxiliary’ wi pe oun lepa ẹmi oun. Idahun ti Ọlọpọeyan fun wa ni pe ko si ohunkohun ti o pa awọn pọ mọ nitori oun ko ba wọn si ninu ẹgbẹ awakọ.

Bakan naa ni Ọlọpọeyan fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu NNPP n’ipinlẹ Ọyọ lo mọ wi pe oun ati Makinde jọ n sọrọ saaju asiko yii, nitori oun ko fi ohunkohun pamọ fun wọn.