Kí gan ni Àbọrú, Àbọyè àti Àbọṣíṣẹ túmọ̀ sí?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

  • Author, Akinlabi Afolabi
  • Role, Broadcast Journalist

Lati bi ọsẹ diẹ sẹyin ni awuyewuye ti n jẹyọ lori lilo Aboru, Abọye ati Abọsisẹ to jẹ ọrọ Yoruba to si ni ibasepọ nla pẹlu awọn isẹẹse ni ilẹ Yoruba.

Ọba Ogboni Iwasẹ, Adeyinka Adisa Sangolade Arifanlajogun, ninu ifọrọwerọ to se pẹlu Ileeṣẹ BBC News Yoruba salaye pe ikinni ni awọn ọrọ mẹẹtẹta yii jẹ ati pe o jẹ nnkan to tọdọ awọn ẹlẹsin isẹẹse wa

O tẹsiwaju pe gbogbo ẹsin lo ni ede ti wọn fi maa ki ara awọn ti wọn ba lọ si ilẹ ara wọn.

Ninu ọrọ tiẹ, Dokita Oluseyi Atanda to jẹ aarẹ gbogbo ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun ni bi awọn musulumi se maa sọ pe Asalamualekun ati bi awọn onigbagbọ ba wipe Alaafia fun ẹni to wa ni ile yii naa ni Abọru, Abọye ati Abọsise jẹ fun awọn to ba fẹ lọ ki Babalawo ni ile.

“O tu mọ si pe ẹ jẹ ki a ri ile wọ, o tu mọ si pe eeyan n ki Babalawo, ti Babalawo yoo si ma da lohun pe , Ogbo, Atọ, Asuure, Iworiwofun.”

Kí gan-an ní à wa ń pè ní Àbọrú, Àbọyè Àbọsísẹ?

Dokita Atanda salaye ni kikun bi ọrọ naa se jade, to si fi di lilo fun awọn ọmọ kaarọ orijire, paapa awọn onisẹẹse.

Ninu alaye rẹ, Atanda ni nigba ti Ọrunmila fẹ se awọn nkankan, to n lọ si ode ọọrun, Ọrunmila kọ lati kan saara si awọn Obinrin mẹta kan ti orukọ awọn Obinrin yii n jẹ Abọru, Abọye ati Abọsisẹ.

Ẹ gbọ alaye:

“Orunmila ko naa ni awọn obinrin yii, eyi lo fa ti ko fi ri nkan to fẹ se se, wọn wa sọ fun pe awọn mẹta to salapade ni ẹnu ọna, o ni lati fi ti wọn se, ati pe to ba fi ti wọn se, gbogbo nkan to fẹ maa jasi irọnu.

“Orumila wa rubọ, nigba to pada lọ si bẹ, o wa kan sara si awọn obinrin mẹta yii, o kan ilẹkun, awọn obinrin mẹta yii wa si ilẹkun,

“Nigba ti wọn si ilẹkun fun, ohun to rọ pe o ma le fun un lati se wa jasi irọnu. Orunmila wa ro pe bi awọn obinrin yii se ran oun lọwọ, njẹ wọn yoo gba lati tẹ le oun lọ ile ki wọn si di iyawo rẹ,

“Awọn Obinrin mẹtẹẹta si gba lati di Iyawo Orumila, ti wọn si tẹle lọ si ile.

“Ọrunmila tun wa ro pe ki ni oun le se lati fi se aponle awọn obinrin mẹtẹẹta yii nitori awọn ni wọn silẹkun fun un lati ri ọna wọle, fun idi eyi, ẹmikẹni to ba ti n bọ lọdọ Babalawo, to fẹ ba oju rere Babalawo pade, ko kọ kọ maa kan sara si awọn obinrin yii ti wọn jẹ iyawo rẹ,

“Ohun lo fi di pe di ọla ode yii, ti eeyan ba fẹ kan ilẹkun Babalawo, o gbọdọ sọ pe Abọru. Abọye, Abọsisẹ, bi ki eeyan ni oun wọle pẹlu Alaafia.”

Dokita tẹsiwaje pe awọn orukọ wọnyi ni itumọ nitori pe lowe lowe ni ọrọ ifa.

“Ẹni to n wọle bọ to ni Abọru, Abọye, Abọsisẹ n se adura fun Babalawo wipe bi o se n bọ, ti o n ru yoo maa ye, Olodunmare yoo ma fi asẹ si lẹnu.

“Babalawo yoo wa n fesi pe Ogbo, Atọ, to tumọ si pe iwọ naa wa gbo, wa tọ.”

Nje awọn ẹlẹsin miiran le lo Abọru, Abọye ati Abọsisẹ?

Ọba Ogboni iwasẹ, Adeyinka Adisa Sangolade Arifanlajogun tẹnu bọ ọrọ pe ko si nnkan to buru ninu pe ki awọn ẹlẹsin miiran lo Abọru, Abọye, Abọsisẹ ninu ijọsin wọn sugbọn ẹni to ba lo awọn ọrọ yii gbọdọ mọ pe oun ti darapọ mọ ẹsin iwasẹ niyẹn nitori o mọ itumọ rẹ.

“Ohun to ba le fi mu ẹlẹsin miiran sọ pe Abọru, Abọye Abọsisẹ, dajudaju oun naa ti darapọ mọ ẹsin iwasẹ niyẹn

“Irufẹ eeyan bẹ mọ itumọ awọn ọrọ yii, lo se sọ sita, nitori ẹni ti ko ba mọ itumọ rẹ ko ni sọ sita.

“Fun idi eyi, ko lodi fun ẹsin miiran lati lo sọ pe Abọru, Abọye Abọsisẹ.”

Awọn eeyan gbọdọ mọ pe ọdọ Ifa ni a ti kọkọ ri ọrọ yii – Dokita Atanda

Dokita Oluseyi Atanda ti ọrọ Oba Iwasẹ lẹyin pe Ifa ko sọ pe ki ẹnikẹni ma se lo awọn ọrọ naa sugbọn eeyan gbọdọ mọ itumọ nnkan ti eeyan n sọ sita.

Atanda ni awọn eeyan gbọdọ mọ pe ọdọ Ifa ni ọrọ naa ti jade.

“Nje awọn ẹlẹsin miran yii setan pe ki a ma pe Ọlọrun ni irumọlẹ tabi ki a pe Osa?

“Ti wọn ti gba bẹ, wọn ni ore ọfẹ lati maa lo awọn orukọ wọnyi ati pe nigba to ba ya, o n bọ wa ye ọpọlọpọ.

“Ti wọn ba si n lo awọn ọrọ wọnyi lọ, awa ko ni binu ati pe ọrọ ifa ti n wa si imusẹ nitori Ifa ti n gba aye lọ ni.”