Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ – Ọlọ́pàá Osun

Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, OmoluabiTv

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọrọ lori ibi ti wọn ba iwadii wọn de lori iku to pa ọgbẹni Timothy Adegoke nile itura kan to wa niluu Ile Ife.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Yemisi Opalola sọ fun BBC Yoruba pe awọn ti bẹrẹ ayẹwo oku naa (Pathology), awọn yoo si fi abajade iwadii awọn sita laipẹ.

Opalola lo fidi ọrọ naa mulẹ ni idahun si ibeere ti awọn araalu n beere lori ibi ti wọn ba iṣẹ naa de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ileeṣẹ ọlọpaa ti lọ wu oku ọkunrin naa nibi ti wọn sin si, awọn onimọ ijinlẹ si ti mu lara ẹya ara lọ sinu laabu fun iwadii to peye, eyi ti yoo tu iṣu de isalẹ ikoko irufẹ iku to pa.

O ni “Lẹyin to ku ti wọn si gbe oku rẹ sinu igbo kan ni Ile Ife, a gbera, a si gbe awọn to mọ nipa imọ ijinlẹ bi wọn ṣe maa n ṣe ayẹwo oku lati mọ irufẹ iku to pa oloogbe naa dani, to fi mọ awọn mọlẹbi rẹ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“A n duro de esi ayẹwo patọlọji naa lati mọ igbesẹ ti yoo kan fun wa lori ọrọ ọhun.”

Alukoro ọlọpaa naa sọ siwaju si pe ko si ootọ ninu ọrọ ti awọn eeyan n gbe kiri pe awọn to da ẹmi arakunrin naa legbodo ge ẹya ara rẹ kankan lọ.

O ni “Awọn kan n sọ pe wọn ge apa tabi wọn ge ẹsẹ rẹ, ṣugbọn irọ ni o.”

“Awọn ẹbi oloogbe wa nibẹ nigba ti a ṣe ayẹwo lẹyin ti a wu oku rẹ, gbogbo ohun to wa lara rẹ lo pe, ti awọn ẹbi rẹ si foju wọn ri, a ko mọ ibi ti awọn eeyan ti ri irufẹ awọn iroyin bẹẹ o.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Opalola sọ pe kii ṣe ọrọ ti awọn araalu ba n sọ ni yoo tete jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa tete ri ojutu ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Lori awọn ti ọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ ọhun, Opalola ni eeyan meje lo wa ni ahamọ awọn bayii.

Awọn eeyan naa ni awọn oṣiṣẹ mẹfa lati ile itura ti igbagbọ wa pe iku rẹ ti waye, to fi mọ oludasilẹ ileeṣẹ naa, Ramon Adedoyin.

Awọn akẹkọjade Fasiti oduduwa sọrọ lori iku oloogbe:

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn akẹkọọjade fasiti Oduduwa ti ẹni to ni ile itura ti Adegoke ti ku da silẹ, OOU, ti ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi oju gbogbo awọn to lọwọ ninu iku oloogbe naa lede.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Abamẹta ti wọn pe akọle rẹ ni “Ile itura Hilton kii ṣe fasiti Oduduwa,” ni wọn ti kede ọrọ naa.

Atẹjade ọhun ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Olatunji Olayinka buwọlu sọ pe ile itura Hilton ni iṣẹlẹ naa ti waye, kii ṣe fasiti Oduduwa, nitori naa ki awọn araalu dẹkun ati maa so iṣẹlẹ ọhun pọ mọ fasiti Oduduwa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ