Ìpanu ”small chops” ló mú kí sọ́jà da omi ìdọ̀tí lé mi lórí – Corper Fidelia

NYSC ti sọja na

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Agunbanirọ, Ezeiruaku Ifenyinwa Fidelia, ti sọja obinrin kan, ọgagun Chika Viola Anele da omi idọti le lori, ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gan an laarin awọn mejeeji.

Agunbanirọ Fidelia ṣalaye pe, ọrọ naa bẹrẹ nigba ti awọn lọ si barake awọn ologun fun idije kan niluu Calabar.

”Mo jẹ ọkan lara awọn to n pin ounjẹ nibi eto naa lọjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mo fọwọ kan sọja kan ti a jọ maa n sọrọ lati ki i, ṣugbọn sọja obinrin yii Lt. Anele sọ fun mi pe o lodi sofin fun mi lati fọwọ kan ọmogun.

Mo ni lati pada si ibi ti mo duro si tẹlẹ lẹsẹ kẹsẹ.

Lẹyin naa ni ọga sọja mii na ọwọ si mi nigba to fẹ ki mi, ṣugbọn mo ni lati sọ fun un pe wọn ni a ko gbọdọ ba awọn ọmogun ba ọwọ.

NYSC ti sọja na

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Amọ, Lt. Anele da mi lohun pe mo le bọ ọwọ pẹlu awọn sọja ṣugbọn n ko le fọwọ kan wọn ni.

Bayii ni a bẹrẹ si ni pin nkan ipanu ”Small chop” nibẹ, eleyii ti sọja obinrin yii, Lt. Anele n ṣe agbatẹru rẹ.

O ṣẹlẹ pe ”small chop” sọja kan danu nigba ta fẹ gbe le lọwọ, o si sọ fun mi pe ki n lọ gbe omiran wa foun.

Mo sọ fun un pe o ti tan, ṣugbọn o kọ jalẹ pe ki n lọ ba oun gbe omiran wa.

Bayii ni sọja Anele bẹrẹ si ni fi ọrọ gba mi lori pe oun ti ṣalaye fun mi tẹlẹ pe, nkan ipanu ti tan ayafi ti mo ba fẹ fun sọja ọhun ni eyi ti awa agunbanirọ maa jẹ lo ku.

Mo ṣa mu ninu ”small chop” ti awọn agunbanirọ lọ fun sọja naa, ti o si jẹ ẹ.

Lẹyin idije yii ni Lt. Anele pe emi ati awọn akẹẹgbẹ mi yoku, o da mi yọ sita laarin wọn, ti o si bẹrẹ si ni sọ ọrọ bakungbe si mi pe n ko ni ọpọlọ rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni bawo ni mo ṣe tun wa ba oun lẹyin ti oun ti ṣalaye fun mi pe ”small chop” ti tan.

Lẹyin naa lo pe ipade pẹlu awa agunbanirọ ti o si bẹrẹ si ni ko ilaali fun mi nibẹ.

Lt. Anele ni ki n ma yi ara mọlẹ pẹlu aṣọ NYSC lara mi, mo ni mi o le ṣee.

O tun sọ fun mi pe ki n maa joko idẹra kaakiri, mo tun kọ lati ṣee.

Mo bẹrẹ si ni joko idẹra ṣugbọn nigba ti o ri pe ko eyi ko ni ipa buruku lara mi, o ni ki n kunlẹ ki n si gbe okuta lọwọ.

O ni oun ko ni fi mi silẹ ti oun ko ba ri omi loju mi, ṣugbọn mo ju okuta naa silẹ nigba ti o rẹ mi.

Mo ni lati sọ fun pe n ko le ṣe ohun kankan mọ tori mi o jale, bẹẹ ni n ko si paayan.

Nigba yii gan an lo da omi ati yẹpẹ pọ ti o si bẹrẹ si ni daa le mi lori.

Bayii ni Lt. Anele n da omi idọti le mi lori ti o si n fi ike ibomi gba mi lori ṣugbọn n ko sọ ohun kan tori n ko fẹ ko mọ pe ohun ti o n ṣe fun mi n dun mi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni eyi yoo jẹ ẹkọ fun mi nitori ọjọ mii ṣugbọn n ko sọ ohun kan,” agunbanirọ Fidelia ṣalaye

Ẹwẹ, ile iṣẹ ologun Naijiria ti ni igbẹjọ soja naa ti bẹrẹ ni kiakia wipe awọn yoo fi idiotitọ mulẹ fun awọn araalu lori iṣẹlẹ naa to fi mọ esi iwadii.