“Iná tó ṣẹ́yọ ní UCH Ibadan kò pa ẹnìkẹ́ni lára” – Àwọn alákóso fi ọ̀rọ̀ léde

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Igbimọ alakoso ile iwosan ẹkọṣe iṣegun Oyinbo ti fasiti ilẹ Ibadan, UCH ti ṣe alaye wi pe ko si iredi kankan fun ẹnikẹni lati foya nitori ile iwosan naa yara pa ina to ṣẹyọ lọjọ Abamẹta.

Giwa agba nile iwosan UCH, Ọjọgbọn Abiodun Otegbayo fi ọrọ to awọn oniroyin leti wi pe lọgan ti ina naa ṣẹyọ ni ile iwosan naa ti ke si ileeṣẹ panapana mẹta ọtọọtọ ti wọn si yara de si ibẹ lati pa ina naa.

Otegbayo fi kun ọrọ rẹ pe lọdi si iroyin to n lọ kaakiri wi pe awọn alaisan n bẹ ni apa ibi ti ina ti ṣẹyọ ni igun ti wọn ti n tọju awọn aisan to gboro, ICU, ati apa ibi ti wọn ti n ṣe iṣẹ abẹ nile iwosan naa, o ni ko si ohunkohun to jọ bẹẹ.

Awọn alakoso ile iwosan naa fi idaniloju han fun mọlẹbi awọn alaisan to n bẹ lọdọ wọn wi pe ki wọn ma foya nitori ohun gbogbo ti pada bọ sipo, bẹẹ sini iṣẹ ti bẹrẹ pada pẹlu awọn ọna mii ti wọn gbe itọju alaisan gba.