Iléẹ̀kọ́ Chrisland sọ̀rọ̀ jáde lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ wọn, Whitney Adeniran

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn alasẹ ileẹkọ Chrisland College ti sọrọ jade lori iṣẹlẹ kan to waye ni ileẹkọ naa, eyi to mu ẹmi ọkan lara awọn akẹkọọ wọn Whitney Adeniran lọ.

Arabinrin Blessing Adeniran to jẹ iya ọmọbinrin naa lo salaye bi ọmọ rẹ, Adesola Adeniran sẹ di oloogbe lasiko ere idaraya ojule-si-ojule, inter-house sport ti ileẹkọ Chrisland College.

Arabinrin Blessing naa kegbajare lori ẹrọ ayelujara nibi to ti sọ iriri rẹ ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Keji, ọdun 2023.

Ninu atẹjade ti ileẹkọ naa gbejade loni, wọn ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni awọn fi n kede ipapode ọkan lara akẹkọọ wọn, ẹni to jade laye lọjọbọ, Ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun 2023.

“Inu wa bajẹ nitori ọkan lara ọmọ wa ni Whitney to ni ko wu ohun lati kopa ninu ere idaraya ojule-si-ojule nitori idi kan tabi omiran ti a ko mọ.

“Lọgunjọ, oṣu kini ọdun yii, a pe akiyesi awọn obi ọmọ yii nigba to sọ fun wa pe oun ko mọ bi o ṣe ṣe oun ni ago ara.

“Baba ọmọ, Michael Adeniran, wa si ileẹkọ lati wa mu ọmọ naa lọ si ile. A rọ awọn obi lati tọ ju ọmọ naa.”

Ileẹkọ naa ni oloogbe naa sa dede suubu ni itagbangba, ti wọn si sure gbe lọ si ilewosan to sumọ ileẹkọ naa fun itọju.

A rọ awọn obi ọmọ naa lati ṣe ayẹwo lati mọ iru iku to pa Whitney

Ileẹkọ Chrisland ti wa rọ awọn mọlẹbi Adeniran lati ṣe ayẹwo lori iku to pa ọmọ wọn ki wọn to gbe lọ sin.

“A ti fi to awọn akọsẹmọsẹ leti lori bi iwadi lori ayẹwo naa yo ṣe waye, ti a ko si fi iroyin mii lede nitori ọmọ kekere ni oloogbe naa, ti a si gbọdọ bọwọ fun oun ati mọlẹbi rẹ.

“A ba mọlẹbi Adeniran kẹdun, ibanujẹ nla lo jẹ fun wa, ti a si gba ladura pe Ọlọrun duro ti wọn lasiko ti wọn wa yii.”

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ mi tó fò ṣàńlẹ̀ kú ní iléẹ̀kọ́ Chrisland? – Iya Whitney Adeniran

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Arabinrin Blessing Adeniran ti sọ bi ọmọ rẹ, Adesola Adeniran sẹ di oloogbe ni asiko ere idaraya ojule-si-ojule, inter-house sport ti ileẹkọ Chrisland College.

Arabinrin Blessing naa kegbajare lori ẹrọ ayelujara nibi to ti sọ iriri rẹ ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Keji, ọdun 2023.

Abilekọ Blessing ni oun ti ṣeleri fun ọmọ oun pe oun yoo wa nibẹ lasiko ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ ere idaraya ti ọdun yii nitori oun ko si nibẹ ni ọdun to kọja.

‘’Ki wọn to bẹrẹ ere idaraya ni mo ti wa nibẹ, ti mo si ki awọn olukọ ọmọ mi to fi mọ olukọ agba ati awọn obi to wa nibẹ.

Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ yiyan bi ologun ‘’March past’’ ti mo si bẹrẹ si ni fi oju wa ọmọ mi amọ mi o ri’’.

Gbogbo awọn eniyan yan kọja, to fi mọ Pine(Green) House to sọ fun mi pe oun wa amọ mi o ri i.

Aya mi bẹrẹ si ni ja ni mo ba lọ si ibi ti wọn ti n ra ipapanu , ti wọn si sọ fun mi pe Winifred kan subu lulẹ nibi yii, ti wọn si rọ omi le lori.

Lẹyin ọpọ igbiyanju arabinrin naa ni oun tẹ ọkọ leti lọ si ileewosan ti wọn sọ fun oun pe ọmọ ọhun wa.

‘’Oku ọmọ ni mo ba ti ahọn ati ete rẹ ti dudu’’

Arabinrin Blessing ni kete ti oun de ileewosan naa ni oun bere ibi ti ọmọ oun wa, ti wọn si juwe ibẹ.

‘’Oku ọmọ mi ni mo ba ti oun sun omi lati ori de eekanna ẹṣẹ’’.

Ibanujẹ mi nipe awọn ileẹkọ Chrisland ko ṣeto iwosan pajawiri kankan silẹ fun awọn akẹkọọ to le ni ẹẹdẹgbẹta ti wọn n ṣere idaraya.’’

‘’Mo mi ọmọ mi titi ko dide, mo kigbe, mo faraya, ọmọ mi ko mi mọ’’

‘’Mo bere lọwọ dokita pe ki lo ṣe ọmọ mi, dokita naa ni boya aisan ọkan, amọ ọmọ mi ko ni aisan kankan.’’

‘’Awọn dokita nibẹ ni wọn gbe ọmọ naa wa si ileewosan pe o si ti ku.’’

Ibeere mi ni pe ki ileẹkọ Chrisland ṣalaye fun mi ki lo pa ọmọ mi Whitney Adeniran?

Iya Whitney Adeniran ni ọmọ oun ko ṣe aisan tẹlẹ, pe ki lo ṣe ọmọ oun.

O ni ibeere ti oun fẹ ki awọn olukọ ileẹkọ naa da wọn lohun pe ki lo ṣẹlẹ.

‘’Kilo ṣẹlẹ si ọmọ mi,ki lo ṣẹlẹ si Whitney Adeniran? Wọn o gbe ọmọ mi lọ si ileewosan, immunisation centre ni wọn gbe ọmọ mi lọ.’’

Arabinrin naa wa kesi ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, awọn alẹnulọrọ ni ilu ati lori ẹrọ ayelujara ki wọn wa dasi ọrọ yii

O ni awọn obi ti n pe oun pe ileẹkọ naa ni ọmọ naa n ṣe aisan amọ o ni kosi nkankan to ṣe ọmọ oun.

Iya ọhun ni oun ko ni dakẹ titi ti oun yoo fi mọ otitọ nipa isẹlẹ naa.

Arabinrin naa wa kesi awọn obi, ọmọ ileẹkọ lati gbogbo awọn eniyan to wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye lati wa sọ fun wọn ohun to ṣẹlẹ