Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá

Aworan Timothy ati Ramon Adedoyin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Timothy Adegoke/Oduduwa University

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kede pe awọn ti mu alaga ati oludasilẹ ile itura Hilton Hotel and Resort, Ile-Ife, Ramon Adegoke Atobatele Adedoyin.

Eyi ko si ṣẹyin iwadii ti wọn lawọn n ṣe lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, OAU, Timothy Adegoke ti wọn ni o de si ile itura Hilton ko to ṣaadede poora.

Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Opalola Yemisi fi ṣọwọ si BBC, o ni ṣaaju ki awọn to mu Adedoyin, awọn ti mu eeyan mẹfa kan ti awọn fura si pe wọn mọ si iku akẹkọọ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Timothy Adegoke la gbọ pe o de si ile itura Hilton lati Abuja lọjọ Kaarun oṣu Kọkanla ti o si fẹ sun sibẹ ki o baa le ribi kopa ninu idanwo ẹka ileẹkọ OAU ti yoo waye lọjọ keji.

Lọjọ Keje Oṣu Kọkanla ni wọn kede pe Adegoke ti di awati lẹyin ti iyawo ati awọn mọlẹbi rẹ ko gburo rẹ mọ.

Lẹyin tawọn mọlẹbi fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Edun Abon Police, wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran iyẹn State Criminal Investigation Department lọjọ Kẹsan oṣu Kọkanla.

Aworan Ramon Adedoyin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oduduwa University

Abalọ ababọ, ọlọpaa lawọn ri oku Adegoke ninu saare kan ti wọn sin in si ti wọn si ti gbe oku naa lọ fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣeku pa.

Bakan naa wọn lawọn ti mu eeyan mẹfa kan tawọn fura si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju ati pe awọn n fi ọrọ wa Ramon Adegoke Atobatele Adedoyin lẹnu lati mọ ohun to ṣẹlẹ gaan.

Ki lo le mu ki wọn ṣeku pa Adegoke ni ile itura to de si?

Ibeere yi lo gba ẹnu awọn eeyan to n fọkan ba ọrọ yi bọ lati igba to ti lu sita.

Onimọ iwe iṣiro ni Adegoke to si fi ilu Abuja ṣe ibujoko.Ẹekọọkan lo n de si ile itura Hilton nitori eto ẹkọ to n ṣe ni ẹka fasiti OAU to wa ni Moro.

Ninu nkan ti ẹgbọn rẹ kan sọ fun gbajugbaja akọroyin nilu Ibadan, Olayomi Hamzat ninu fọnran fidio, awọn oṣiṣẹ ile itura lo gbimọran pọ lati pa Adegoke.

Ọrọ yi ko ti ribi fidi mulẹ lati ọdọ awọn ọlọpaa.

Ni kete ti wọn ba gbe esi iwadii wọn jade, a o maa fi to yin leti