Ilẹ̀ mọ́ bá àwọn adigunjalè tó jí ọkọ̀ gbé ní Kwara, ọlọ́pàá pa ọ̀kan, mẹ́rin fara gbọta

Aworan agbẹnusọ ajọ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejire-Adeyemi Adetoun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun: Owe yii lọ ṣẹ mọ awọn agigunjale ẹlẹni marun-un kan lara n’Ilorin.

Afi bii ere sinima agbelewo lagbegbe Kulende, Zango, Ilorin ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, lori bi ọlọpaa ṣe pa ọkan ninu awọn adigunjale kan, tawọn meji miran si tun fara gbọgbẹ ọta ibọn ki wọn to sa lọ.

Nnkan o ṣẹnuure rara fun ikọ adigunjale ẹlẹni marun-un naa laarọ Ọjọru, ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.

BBC Yoruba gbọ pe n’ilu Ogbomoso, nipinlẹ Oyo, lawọn adigunjale yii ti lọọ ja mọto ayọkẹlẹ Toyota Corolla ati Toyota Camry gba, ti wọn si pin ara wọn si meji – mẹta ninu Toyota Corolla, nigba tawọn meji si wọnu Toyota Camry muscle.

Awọn afurasi adigunjale yii ni wọn fẹẹ gba ilu Ilọrin sa lọ amọ ti wọn pade awọn ọlọpaa lọna, ti awọn ọlọpaa naa si bẹrẹ si nii le wọn.

Bo tilẹ jẹ pe awọn afurasi mẹta to wa ninu Toyota Corolla fara gba ọta ibọn, wọn gbe ọgbẹ naa sa lọ ṣugbọn awọn to wa ninu Toyota Camry ko fi ara ire lọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe lagbegbe Kulende, Zango, niluu Ilọrin, ni ibọn ti ba eyi to n wa Toyota Camry lọrun to si lọọ kọlu opo ina ati awọn ṣọọbu to wa ni agbegbe naa to si ba ọpọ dukia jẹ.

Ọkan ku ninu awọn meji yii ti ẹnikeji si gbe ọgbẹ ọta ibọn sa lọ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, o fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Adetoun wi pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ati pe iwadii si n lọ lọwọ lati mu awọn mẹrin to sa lọ ninu awọn adigunjale naa.