Ijọba Lande fi ẹnu ara rẹ̀ ṣàlàyé ohun tó dé si àti bó ṣe di àwátì

Ijoba Lande

Oríṣun àwòrán, Ijoba Lande

Oṣere ati adẹrinpoṣonu to di awati laipẹ yii, Gamiyu Kehinde, ti ọpọ mọ si Ijoba Lande ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si to fi di awati.

Ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ ati ifọrọwerọ pẹlu awọn mọlẹbi rẹ lo ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ ọhun.

O ni kii ṣe pe ṣe ni wọn ji oun gbe, amọ ṣe ni oun funra oun rin lọ lati lọ gbẹmi ara oun nitori awọn iṣoro kan ti oun koju.

Ninu fidio to ti fi ẹmi imoore han si awọn ọmọ Naijiria atawọn akẹgbẹ rẹ lo ti ṣalaye pe iṣẹlẹ ọhun ko lọwọ ajinigbe ninu.

“Wọn ko ji mi gbe, ifẹ inu ara mi ni mo ṣe”

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun yoo tun pada ṣalaye lẹkunrẹrẹ bi iṣu ṣe ku ti ọbẹ si bu, o ni ifẹ inu ara oun loun ṣe loun ṣe di awati.

Ijoba Lande to n ṣalaye ọrọ naa pẹlu omije loju sọ pe ko si ẹnikeni to ji oun gbe.

O ni “Mi o fẹ gbọ pe wọn ji mi gbe o, ko si ẹni to ji mi gbe.”

Bi irinajo Lande ṣe lọ

Gẹgẹ bii ohun to fi ẹnu ara rẹ sọ fun iyawo atawọn mọlẹbi rẹ, ẹsẹ ara rẹ l o fi rin jade kuro ninu ile lati lọ pa ara rẹ nigba ti aye ti su.

O ni “Lọjọ kẹrindinlọgbọn, ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan an alẹ, emi funra mi ni m pa foonu, ti mo si jade kuro ninu ile.”

Mo kọkọ mu ọbẹ kan lati fi gun ara mi, amọ o ṣoro fun mi lati ṣe bẹẹ nitori ẹru ba mi ati nitori ọmọ kekere ti mo ni sinu ile.”

“Mo fi ọbẹ naa silẹ, mo si jade lọ lati lọ ko sinu odo.”

“Mo fi ẹsẹ rin funra mi lọ si ọna Isefun, nibi Kande, mo duro ki awọn to n ta ọja nibẹ lọ sile wọn tan ki n to bẹ sinu odo .”

Ijoba Lande ṣalaye siwaju si pe nnkan bii aago mejila oru loun gbiyanju lati gbẹmi ara ninu odo naa latari awọn iṣoro to ka oun laya.

“Iṣoro to ka mi laya lo jẹ ki n bẹ sinu odo”

Nigba ti awọn mọlẹbi rẹ n bere lọwọ rẹ eredi to fi gbe igbesẹ naa, Lande sọ pe igbesẹ ọhun ko kọja iṣoro ti oun n dojukọ.

O ni “Nigba mii, isọrọ maa n ka eeyan laya… iṣoro ju iṣoro lọ.”

Lẹyin naa dupẹ lọwọ gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ dun aduroti wọn lasiko ti oun kuro nile, fun adura wọn ati bi wọn ṣe n pariwo lori ayelujara pe oun sọnu.