Ìdìbò 2023: Àwọn ìpèníjà tí Bola Tinubu yóò kojú nínú ìrìnàjò rẹ̀ nìyí

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìgbésẹ̀ adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu láti kéde èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò Ààrẹ lọ́dún 2023 tí fòpin sí àhesọ pé bóyá ó ń gbèrò tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Òdú ni Tinubu nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tó sì kó ipa ribiribi sí ìjáwé olúborí ẹgbẹ́ náà nínú ètò ìdìbò ọdún 2015 àti 2019.

Yàtọ̀ sí èyí Tinubu ti kópa tó lóòrìn sí fífa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ sókè tí oníkálukú wọn sì ń kópa rere ní ààyè kóówá wọn.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí, à ti di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lè má rọrùn fún un látàrí ìwòye àwọn ènìyàn kan bí wọ́n ṣe ṣe àlàyé àti àlàkalẹ̀ àwọn ohun tí ó le jẹ́ ìpèníjà fún un níbi ètò ìdìbò náà.

Ṣé ìlera Tinubu yóò gbé e?

Sanwoolu ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwoolu

Ọ̀jọ̀gbọ́n Kamilu Sani Fagge, tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Bayero, Kano ni ọkàn lára àwọn ohun tí yóò jẹ ìpèníjà fún Tinubu ni lati rí tíkẹ̀tì ẹgbẹ́ gbà.

Ohun kejì tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Fagge wòye pé ó le ṣe ìdíwọ́ fún Tinubu ni ìlera rẹ̀. Ọ̀pọ̀ oṣù ni Asiwaju Tinubu lò ní ìlú London lọ́dún tó kọjá látàrí àìlera.

O pẹ to bẹẹ gẹ ti ọpọlọpọ awọn eekan oloṣelu to fi mọ awọn gomina ipinlẹ lọ n ṣe ibẹwo sii ni ilu London.

Ó ní ìlera pípé ṣe pàtàkì fún ẹnikẹ́ni tí yóò bá darí Nàìjíríà pàápàá lásìkò yìí tí àwọn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń pòùngbẹ Ààrẹ ọ̀dọ́.

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Fagge ṣe sọ, bi o ba jẹ awọn ibomii ni, wọn ko tilẹ ni darukọ rẹ tori ailera bẹẹ si ni oun funrarẹ ko ni fọhun.

“A ti ri awọn adari mii latẹyin wa to jẹ pe tori ara wọn ko le, o ṣakoba fun iṣejọba ọhun gidi gan. Ohun taa mọ ni pe ara Tinubu ko ya botilẹ jẹ pe a o le sọ ni taara bo ṣe jẹ.

Àwọn Gómìnà ẹgbẹ́ APC kọ̀ọ̀kan

Awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu APC

Oríṣun àwòrán, FEMI ADESINA

Bákan náà ló tún wòye pé àwọn gómìnà tí wọ́n ti ń gbèrò láti du ipò Ààrẹ tàbí igbá-kejì tí wọ́n sì nílò àtìlẹyìn Tinubu yóò jẹ́ ìṣòro fún un kí èròńgbà rẹ̀ tó le wá sí ìmúṣẹ.

“Awọn kan lara wọn naa ti gbe apoti idibo, awọn mii jẹ adari ẹgbẹ oṣelu, ninu awọn to n lọ fun ipo aarẹ ti wọn si ri Tinubu niwaju wọn ninu idije kan naa, wọn n woye pe nini Tinubu niwaju lee dina erongba awọn.

Ni ti awọn to fẹ jẹ igbakeji aarẹ, wọn woye pe bi Tinubu ba ti le pinu lati dibo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, yoo nira fun ọpọlọpọ wọn lati ri ipo naa gba tori pe wọn jọ jẹ Musulumi si Musulumi ni amọ gẹgẹ bi ofin ṣe gba a laye, bi aarẹ ba jẹ Musulumi, igbakeji gbudọ jẹ Kristẹni.

“Koda lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba, ẹ o le ni gbogbo gomina lo n ti Tinubu lẹyin, meji ninu wọn lo n tii lẹyin” gẹgẹ bi Ọmọwe Kari ṣe sọ ọ.

Ọmọwe Kari fi kun un pe igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo lee jẹ eegun lọna ọfun Tinubu gidi gan tori o han gbangba pe awọn to sunmọ aarẹ timọ timọ kan wa ti ki ko fẹran Tinubu eyi ti yoo si nira fun wọn lati gbaruku tii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“APC máa ń kùnà láti mú ìlérí ṣẹ”

Idanimọ ẹgbẹ APC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lára àwọn ohun tí ó lè ṣe ìdíwọ́ fún Tinubu gẹ́gẹ́ bí Fagge ṣe sọ ni pé, àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé gbogbo àdéhùn tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣaájú ètò idibo ọdún 2015 pàápàá lórí ètò ààbò, ìwà àjẹbánu àti eto ọrọ̀ ajé ni kò jẹ́ mímúṣè.

Ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe awọn ileri kan fun awọn ọmọ Naijiria lasiko ti wọn n polongo ibo lọdun 2015 paapaa nipa kikoju iṣoro abo, kikoju iwa ajẹbanu, ṣiṣe agbende ọrọ aje amọ ninu gbogbo eyi, awọn kan gbagbọ pe ko si ikankan ninu awn ileri yii ti ẹgb naa muṣẹ.

Ó ní àìníṣẹ́, ọ̀wọ́n gógó àti ìṣẹ́ òhun òṣì ló gba ìlú kan lòdì sí ìlérí ẹgbẹ́ èyí tí Tinubu jẹ́ abẹnugan rẹ̀ lọ́dún 2015 to polowo ẹgbẹ yii fun Naijiria ti wọn fi ra a.

Torinaa, igbagbọ awọn mii ni pe Tinubu gaan ni oguna-gbongbo to wa nidii ijakulẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kò sí àrídájú ìlú tí Tinubu ti wá, kí ni ọjọ́ orí rẹ̀ àti ìdí ọrọ̀ rẹ̀?

Tinubu bá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Edo sọ̀rọ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò hàn sí àwọn ènìyàn nípa Tinubu bíi ìlú rẹ̀, iye ọjọ́ orí rẹ̀ àti pàápàá báwo ló ṣe kó ọrọ̀ rẹ̀ jọ.

Ó ní Tinubu náà kò fi ìgbà kankan fèsì sí àwọn ìbéèrè yìí rí.

Koda, o fi kun un pe awọn ibeere pataki kan ṣi wa to ṣi n fa ọrọ jade to si jẹ pe bi awọn araalu o ba ri esi rẹ, ipenija ṣi n bẹ niwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tinubu ní àtamọ́ ọ̀rọ̀ oṣèlú pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Kano

Kwankwaso ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, KWANKWASIYYA REPORTERS

Ẹlòmíràn tó tún bá ọkọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀, Ọ̀mọ̀wé Abubakar Kárí ní Ìpínlẹ̀ Kano náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèníjà tí Tinubu yóò koju nítorí ibẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbò ti máa ń wá.

Kari ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátìlẹyìn Tinubu tí ń tàn ká Ìpínlẹ̀ Kano, àwọn kan gbàgbọ́ pé ó wà lára àwọn tó ń fa làásìgbò tó ń wáyé lágbo òṣèlú Ìpínlẹ̀ náà pàápàá lórí ètò ìdìbò ọdún 2019.

Nibayii, awọn adari kọọkan ni ipinlẹ Kano ti n fi atilẹyin wọn han fun un koda titi de ori ayelujara.

Lafikun, gomina ipinlẹ Kano gan, Abdullahi Umar Ganduje wa lara awọn to fojuhan gẹ́gẹ́ bí igbákejì tí wọ́n bá fẹnu kò pé kí Mùsùlùmí méjì díje.