Ìdí rèé tí mo ṣe fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà – Tinubu

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Yoruba ni ti ko ba si ẹṣẹ, ẹṣẹ kii dede sẹ, bi ko ba si ni idi, obinrin kii jẹ Kumolu.

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu, ti salaye idi to se fẹ dije fun ipo aarẹ Naijiria.

Tinubu se alaye lori idi to se fẹ jẹ aarẹ lasiko to n fikunlukun pẹlu igbimọ awọn ọba alaye nipinlẹ Ekiti ni Ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu, to ti jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko lo ti kede sita saaju pe oun fẹ dije gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ APC naa.

Bakan naa si lo ti n lọ kaakiri igun mẹrẹẹrin Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba, lati kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn eeyan lo si ti n se ariwisi lori ikede Tinubu naa, ti wọn si n beere pe se ilera ati ọjọ ori rẹ gbe ẹru ipo aarẹ Naijiria?

Koda, wọn tun n beere pe ki lo tun n wa lẹyin to ti jẹ Gomina, to si tun jẹ afọbajẹ fun aimọye aarẹ ati gomina to ti jẹ lorilẹede Naijiria.

Nibayii, Bola ti nubu ti wa fesi sita fun araye ati awọn alariwisi rẹ lori ohun to mumu laya rẹ, to se fẹ gba akoso Naijiria bii aarẹ.

Idi ree ti mo se fẹ dije fun ipo aarẹ Naijiria:

Ninu alaye rẹ, Tinubu ni oun fẹ pese ọjọ ọla to duro re silẹ fun iran to n bọ, ni oun se fi ara oun silẹ lati dije fun ipo aarẹ.

Bakan naa ni asaaju ẹgbẹ APC yii salaye pe Naijiria nilo asaaju rere ni kiakia, ti yoo mu irẹpọ pada saarin awọn ẹya ati ede to wa lorilẹede yii.

“A ti yan isejọba awa ara wa, a ko si gbọdọ kuna ninu ojuse wa. Mo fẹ dije lati sọ ireti awọn ọmọ Naijiria ninu orilẹede yii dọtun.

Bakan naa ni mo tun fẹ ki ọjọ ọla rere to dara wa fawọn ọmọ wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Orilẹede Naijiria nilo asaaju ti yoo sọ eto aabo to mẹhẹ di ohun itan, ti yoo si tun mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ati igbayegbadun araalu.”

Tinubu tun tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe “A ti jijagbara fun eto isejọba alagbada, lonii, a si ti ni eto iselu alagbada naa amọ ko tii fẹsẹ rinlẹ.

Lasiko yii, o ti yẹ ka ni ilana eto ọgbin to ru gọgọ atawọn anfaani lati maa pese ọja fawọn orilẹede miran lati ra.

Ta ba wa fẹ ki Naijiria wa ni isọkan, ko si ni idagbasoke to yẹ, a nilo ọgbọn ati suuru.

Bakan naa si la gbọdọ ni irẹpọ laarin ara wa, ọna kan soso ta fi le de ibi giga ree.

Awọn ilana yii si ni pepele ta duro le lori lasiko ta n da ẹgbẹ oselu APC silẹ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ