Ìdá àádọ́rùn ún àwọn tó ṣe ìdánwò ọlọ́pàá ló fìdí rẹmi – Àjọ ọlọ́pàá

Awọn ọlọpaa kan n yan bi ologun

Oríṣun àwòrán, Nigeria police/ twitter

Ajọ to n ṣamojuto ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Police Service Commission (PSC) ti sọ pe ida aadọrun awọn to joko ṣe idanwo igbaniwọle si iṣẹ ọlọpaa ni wọn fidirẹmi ninu idanwo naa.

Alamojuto fun ọrọ gbogbo to nii ṣe pẹlu ẹtọ ọmọniyan lajọ to n ṣamojuto ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Police Service Commission (PSC), Amofin Rommy Mom lo sọ eyi di mimọ ni ilu Makurdi, ni ipinlẹ Benue.

Amofin Mom woye pe ohun to bani ninujẹ gidi ni pe ida aadọrun awọn to joko ṣe idanwo igbaniwọle si iṣẹ ọlọpaa ni wọn ko lee gba ida ọgbọn ninu ọgọrun maaki ninu idanwo ti wọn ṣe fun wọn.

O wa fi kun un pe ajọ naa ti wa ṣe ara rẹ giri bayii lati wa wọrọkọ fi ṣada lori wiwagbo dẹkun si ipenija bi awọn to fẹ gba iṣẹ ọlọpaa ṣe n fidi rẹmi.

O ni o ya ajọ naa lẹnu pe omilẹgbẹ awọn to joko ṣe idanwo naa ni wọn ku diẹ kaato ni ti ọrọ imọ iwe eleyi to ni o bani ninujẹ pẹlu irufẹ awọn agbofinro ti yoo ti ara awọn eeyan bẹẹ jade bi wọn ba ṣe bẹẹ rapala wọ iṣẹ ọlọpaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O fi kun un pe ẹka to ṣe pataki pupọ ni ẹka abo jẹ, ko si yẹ ko jẹ awọn ti ọpọlọ wọn ti dogun lawujọ ni yoo wa maa ri iṣẹ̀ ọlọpaa gẹgẹ bi ibi ti awọn lee fi ara wọ si.

“Awujọ wa gbọdọ ṣe koriya fun awọn eeyan ọlọpọlọ pipe lati wa dara pọ mọ iṣẹ ọlọpaa lọjọ iwaju. Bi a ba n b’omi tutu sọkan awọn ọdọ to jafafa lati ma dara pọ mọ iṣẹ ọlọpaa, yoo da aṣọ dudu boju ala rere ti awujọ wa ni fun awọn ọlọpaa ni.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ