Iṣẹ́ olùkọ́ kò lówó lórí àmọ́ ó ní ipa púpọ̀ ju iṣẹ́ tíátà lọ fún mi – Saka

Afeez Oyetoro

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Afeez Oyetoro tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Saka ti ṣàlàyé bó ṣe ń kó iṣẹ́ tíátà papọ̀ mọ́ iṣẹ́ olùkọ́ tó ń ṣe.

Saka nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣe pẹ̀lú ìwé ìròyìn PUNCH ní òun máa ń ṣe àmójútó àwọn àkókò òun dáadáa ni òun fi ń rí àwón i’sẹ́ méjéèjì náà kó papọ̀.

Ó ní ṣíṣe àmúlò àsìkò òun dáadáa ló jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ náà rọrùn fún òun láti kó pọ̀ àti pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun máa ń lo àwọn àkókò òun láti fi ṣe ohun tó máa mú èrè wọlé fún òun.

Irọ́ ni, bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ọ̀rọ̀ rí – ìjọba Sweden

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń pe òun sínú eré ni wọ́n mọ̀ wí pé olùkọ́ ni òun nítorí òpin ọ̀sẹ̀ tàbí àsìkò ìsinmi ni wọ́n sábà máa ń fi iṣẹ́ eré yíyà òun sí.

Bákan náà ló ní ipa tí ìyàwó òun ń kó nínú ọ̀rọ̀ òun kò kéré rárá ítorí ó ti mọ irú i’sẹ́ tí òun yàn láàyò.

Saka ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun máa ń sọ fún àwọn ènìyàn láti fẹ́ ìyàwó tó ní àfojúsùn kan náà pẹ̀lú ènìyàn kí ìgbé ayé àwọn méjéèjì lè ba à rọrùn.

“Mo ní ìyàwó tó ń tọ́jú mi dáadáa nílé, èmi àti ìyáwó mi gbọ́ ahọ́n ara wa yé dáadáa débi wí pé kìí sí wàhálà kankan nílé.”

“Ọkàn mi máa ń balẹ̀ tí mo bá ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan tí mò ń ṣe, mó sì tún ní àsìkò láti máa fi sinmi.”

‘Inú mi máa ń dùn tí mo bá rí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ mi níbi gíga’

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí pé iṣẹ́ wo ló lérè fún-un jìlọ nínú àwọn iṣẹ́ méjéèjì tó yàn láàyò, Saka ní iṣẹ́ méjéèjì ló ní èrè tí wọ́n ń mú wá fún òun.

Ó ní gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, inú òun máa ń dùn pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti gba ara òun kọjá dé ààyè gíga ní èyí tó máa ń jẹ́ ìbàlẹ̀ ọkàn fún òun.

“Mo lọ sí Abuja láìpẹ́ yìí láti lọ rí ọ̀kan lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àpọ́nlé tí wọ́n ṣe fún mi pọ̀ púpọ̀.”

“Jíjẹ́ olùkọ́ ní àwọn èrè tirẹ̀ èyí tí kìí ṣe owó lọ́pọ̀ ìgbà.”

Ó fi kun pé iṣẹ́ tíátà lówó lórí ju iṣẹ́ olùkọ́ lọ àti pé i’sẹ́ méjéèjì jọ ara wọn nípa ẹ̀kọ́ tí àwọn fi ń kọ́ àwọn ènìyàn.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ olùkọ́ máa ń wáyé ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, iṣẹ́ tíátà kìí ṣe èyí tó máa ń wáyé nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ àmọ́ iṣẹ́ kan náà ni àwọn méjéèjì ń ṣe.