Gbé ọmọdé ní ìyàwó kí o sì fi ẹ̀wọn ọdún 12 gbára lábẹ́ òfin tí Ààrẹ buwọ́lù

Child marriage

Oríṣun àwòrán, AJ+

Aarẹ orileede Phillippines, Rodrigo Duterte, tí buwọ́lù ofin tó sọ fifi ọmọde fun ọkọ di ẹsẹ tó ní ijiya labẹ ofin.

Gẹgẹ baa ṣe rí ka ninu awọn iwe aṣẹ to jade, ẹwọn ọdun mejila ni ẹnikẹni tó bá wu iru iwà yi yóò fi gbara.

Lọjọ Kẹwa oṣù Kejìlá ọdun 2021 lo fọwọ sí ofin yii.

Ninu rẹ, wọn ka silẹ pe ìjọba ri “fifi ọmọde fun ọkọ gẹgẹ bí iwa ifiyajẹ ọmọde, eleyi to tabuku tó sì yẹpẹrẹ awọn ọmọde naa.”

Labẹ òfin yii, ẹni to ba fi ọmọde fun ọkọ tàbí to se agbatẹru fifi ọmọde fun ọkọ le se ẹwọn ọdun mẹfa sí mejila pẹlu owo itanran.

Wọn tun le gbà irufẹ ọmọ bẹẹ kuro lọwọ obi tabi alagbatọ to ba se iru ẹ.

Bẹẹ lofin táa n wí yi tun sọ pe ẹnikẹni tó bá gbé ọmọde sile bi iyawo lọnà aitọ, yóò fi ẹwọn ọdun mẹfa tabi mejila gbára pẹlu owó itanran.

Ko sí eyikeyi igbeyawo pẹlu ọmọde ti ofin tuntun yi faaye gba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ajọ Oxfam International sọ pé, o kere tan awọn 726,000 ọmọdebinrin lawon eeyan n gbe ni’yawo lorileede Phillippines eleyi to mu ki wọn jẹ orile-ede kejila lori iwọn ti iru iṣesi yi ti n waye julọ.

Apa guusu ilẹ naa tii ṣe Mindanao ni iṣesi yi ti pọju lọ papaa laarin awọn Musulumi to n fẹ ju iyawo kan lọ.

Lagbegbe yi, wọn a máa n fẹ awọn ọmọdebinrin tọjọ orí wọn kò ju ọdun mẹtala lọ.

Awọn aiṣedede ati dọgbadọgba to n waye láwùjọ a máa ṣe okunfa iru isesi yi paapa laarin awọn ti ko rọwọ họri láwùjọ ati l’awọn ibi ti ikọlu ba ti n waye.

Ireti ijọba ni pe “ofin tuntun yi yoo yi awọn aṣa atijọ ti ko da to pada.”