Fídíò, Àlfàá ò bá mi jà, Babaláwo ò bá mi jà, ẹ jẹ́ kí n sọ ìdí táwọn Krìstẹ́nì ṣe ń bínú tórí ìwàásù “hell fire” – Mummy G.O, Duration 6,08

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Mummy G.O: Ẹ bi àwọn tó ti mulẹ nínú ayé gidi, wọ́n mọ̀ wípé òótọ́ ni mò ń sọ – Evangelist Funmilayo Adebayo

Ko sẹni to fi bẹẹ mọ Ajihinrere Funmilayo tẹlẹ ni ijọ rẹ to duro si jẹjẹ to ti n waasu amọ kete ti awn kan gbọ pe o n waasu pe awọn kan yoo lọ ọrun apaadi tori iwa wọn, awọn eeyan han an to si ti tara eyi di gbajugbaja lori ayelujara.

“Wọ́n ń ru ìbínú àwọn èèyàn sí mi ni wọn ṣe n tun gbogbo iwaasu mi “edit” ti wọn n fi ọrọ tiwọn kun un”.

Evangelist Funmilayo Adebayo gangan ni orukọ arabinrin oniwaasu ti gbogbo aye n pe ni Mummy G.O lori ayelujara ti gbogbo eeyan si n fẹ lati wo awọn fidio iwaasu rẹ.

Koda o ti kọja wiwo fidio iwaasu rẹ nikan, awọn eeyan ti n lo aworan rẹ ati ọrọ rẹ lati fi ba ara wọn ṣe yẹyẹ lori ayelujara pe boo ba ṣe bayi bayi, ọrun apaadi lo n lọ.

Eyi wa lara ọrọ to saba maa n jade lẹnu Ajihinrere Funmilayo tori o maa n waasu pe awọn iwa mii ati igbe aye ti awọn eeyan n gbe gaan ni yoo ran wọn lọ si ọrun apaadi eyi tii ṣe inu ina ajooku titi ayeraye eyi ti awọn ọmọlẹyin Kristi gbagbọ pe o jẹ ibi ijiya ayeraye fun awọn ti ko ba gba Jesu Kristi gbọ nigba ti wọn wa ninu aye.

Lara awọn ọrọ to ti jẹyọ ninu iwaasu Ajihinrere yii ti awọn eeyan gbọ ti wọn fi n pariwo niwọnyii:

-Iwọ too ba n fi irun onirun kun irun rẹ ti wọn n pe ni “attachment” ọrun apaadi lo n lọ.

-Iwọ too ba n ṣe iṣẹ apanilẹrin, ko si ijọba ọrun rere fun ọ tori oo le ṣe koo ma pa irọ.

-Iwọ too ba fẹran ere bọọlu tabi too tilẹ n gba bọọlu, inu ina janto.

-Iwọ to ba n kun eekana lọda, ọrun apaadi lo n lọ

Mummy G.O to jẹ oludasilẹ ati adari ijọ Rapture Proclaimer Evangelical Church of God tọka si ibi ti awọn ọrọ to n sọ yii wa ninu bibeli to si ni o n pariwo rẹ faraye tori bibeli lo sọ bẹẹ lai wo ti pe wọn korira oun.

Ajinhinrere yii ni oun ko bikita bi awọn eeyan ba korira oun fun otitọ tori nigba ti oun wa ninu ẹgbẹ okunkun, gbogbo wọn lo fi ifẹ han si oun. Ninu ẹgbẹ okunkun to wa tẹlẹ yii lo ti tọka si pe awọn lawọn pese gbogbo awọn irun afikun irun ati ọpọlọpọ ọṣọ ara ati ipara to si ni ki awọn eeyan jawọ lilo wọn tori oun toun da wọn gan ti faye oun fun Jesu.