Ewú n bẹ̀ nínú ṣíṣe ádùrá nínú igbó, kẹ́ má bà kó sọ́wọ́ ajínigbé – ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀

Aworan awọn aladura ninu igbo

Oríṣun àwòrán, Oasis of God Tv

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn olujọsin lati yago fun ṣiṣe adura ninu igbo, ki wọn ma ba ko si ọwọ awọn ajinigbe.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita gba latọwọ alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ileesẹ ọlọpaa ni ilu ti le kọja ki eeyan maa fi ara rẹ sinu ewu adura ṣiṣe ninu igbo.

Oyeyemi sọ pe bo tilẹ jẹ wi pe awọn araalu lẹtọ lati jọsin, amọ wọn ko gbọdọ maa ṣe adura lawọn agbegbe to ba da paro paro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni iwe mimọ ni bi a baa n ṣe adura, ki a ma sun asunpara bakan naa.

Lọpọ awọn igbo to wa ni ipinlẹ Ogun, ṣiṣe eto isin adura paapa fawọn ẹlẹsin Kristẹni jẹ nkan to wọpọ.

Ipenija aabo lẹnu ọjọ mẹta yii si ṣe okunfa bi awọn ajinigbe ti ṣe n sa si abẹ igbo kijikiji lati ji awọn eeyan gbe, nibi ti wọn ba ti n ṣe ijọsin tabi iṣẹ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ni ipinlẹ Ogun paapa lawọn ilu to ba sun mọ igbo tabi ibode pẹlu orileede mii bi Benin, iṣẹlẹ ijinigbe ko jẹ tuntun.

Oyeyemi ṣalaye pe, iṣẹ ipese aabo yii, ti gbogbo ara ilu nii ṣe, tori naa, kawọn araalu daabo bo ara wọn ati dukia wọn.

Amọ ṣa, o ni ti o ba wa di dandan ki wọn ṣe ijọsin adura wọn yii, ki wọn kan si agọ ọlọpaa to wa ni itosi wọn fun aabo tabi imọran to peye.