Èrò àwọn ènìyàn ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí Gómínà tuntun ní Osun sẹ yọ àwọn Oríadé ní ipò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori igbeṣẹ ti gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura wọle fun, Ademọla Adeleke gbe laarin ọjọ kan to de ipo.

Lara igbeṣẹ naa ni yiyọ awọn ori ade ni ipo pẹlu aṣẹ pe ki wọn yẹba kuro ni aafin.

Ọjọ Aje, to jẹ ọjọ́ akọkọ rẹ lẹnu isẹ, ni Gomina Adeleke pa àṣẹ pe ki wọn o ti aafin ọba ilu Ikirun, Iree ati Igbajo pa.

Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, agbẹnusọ fun gomina, Mallam Olawale Rasheed, sọ pe gbogbo àwọn ọba, ati ìfinijoyè míì to waye lẹyin ọjọ́ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ti di fifa igi lé titi atungbe yẹwo wọn yoo fi waye.

Amọ bi awọn kan se n gboriyin fun igbese gomina Adeleke yii ni awọn miran  to fi ero wọn han bu ẹnu atẹ lu u

‘’Nkan to yẹ ọba to ba ti darapọ mọ oṣelu niyẹn’’

Arakunrin Adeyemo samson to fi ero rẹ han loju opo Facebook BBC Yoruba ni ọkurin ogun ni Ademola Ademola, ti ko si fi akoko ṣọfun rara.

Awọn miran to tun satilẹyin fun ni Edua wa lẹyin rẹ ki o maa tẹsiwaju, lai wọ ẹyin tabi ohun ti awọn alahesọ nsọ.

Bakan naa ni Ajayi Jamiu Damilọla ni pupọ ninu awọn ọba lo jẹ alatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC, ti wọn si n tẹlẹ aṣẹ gomina to kọja.

Ninu ọrọ rẹ, o ni eyi yoo kọ awọn ọba ni ọgbọn lati maṣe fi ọrọ oṣelu ṣe, amọ ki wọn jẹ ọba fun gbogbo ara ilu lai fi si ibi kan.

Amọ awọn ẹlomiran to bu ẹnu atẹ lu gomina naa ni o ti ya ju lati maa gbe iru igbeṣẹ yii ni aiti ju ọjọ kan to de ori oye.

Aworan
Aworan

‘’Aini onimọran to peye n daamu gomina Adeleke’’

 Ninu ọrọ rẹ, Akindele lekan sheriff  ni ijọba Adeleke ti fi ori ṣanpọn lati ibẹrẹ pẹlu bi o ṣe yọ awọn ọba ni ipo.

O fikun un pe ipo ọba, ipo ẹlẹgẹ ni ti ko yẹ ki gomina naa maa dasi ọrọ ipo Ọba alade ni ilẹ Yoruba.

Olanike Akinwunmi ni ero tirẹ ni aini awọn olubanidamọran to peye lo mu ki gomina gbe iru igbeṣẹ yii nitori  to ba bajẹ tan, gomina ọhun nikan lo ku ti yoo fori fa.

Bakan naa ni Funsho Erayetan ni ko yẹ ki gomina Adeleke koju ija si awọn lọbalọba nitori o yẹ ki o ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn ni, kii ṣe ko fi wọn ṣe atẹmẹrẹ.

Aworan
Aworan

Ẹ yẹ̀bá kúrò láàfin ná, mó fẹ́ ṣèwádìí bí ẹ ṣe d’órí ìtẹ́, Adeleke pàṣẹ fún àwọn ọba Ikirun, Iree àti Igbajọ

Ademola Adeleke

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti paṣẹ pe ki wọn o ti aafin ọba ilu Ikirun, Iree ati Igbajo pa.

Ọjọ Aje, to jẹ ọjọ́ akọkọ rẹ lẹnu isẹ, ni Gomina Adeleke pa àṣẹ naa, to si ni kí awọn oṣiṣẹ alaabo gbakoso wọn.

Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, agbẹnusọ fun gomina, Mallam Olawale Rasheed, sọ pe gbogbo àwọn ọba, ati ìfinijoyè míì to waye lẹyin ọjọ́ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ti di fifa igi lé titi atungbe yẹwo wọn yoo fi waye.

“Gbogbo ọba ti ìjọba ipinlẹ Osun fi jẹ lẹyin ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ni àṣẹ ti wà lati ṣe atungbe yẹwo wọn yóò waye”.  

“Eyi jẹ ọna lati ríi daju pe wọn tẹle ila oye jijẹ, to fi mọ àṣà ati ìṣe, to wa fun òye kọọkan.”

Mallam Olawale Rasheed sọ pe gomina ti da eto ọba jíjẹ Akirun ti Ikirun, Aare ti Ire ati Ọwá ti Igbajo, duro nitori ki opin le ba rògbòdìyàn to n waye nibẹ.

Àṣẹ naa tun sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ duro ninu awọn aafin ìlú naa titi di asiko ti ijọba bá ṣi wọn pada.

Lati igba ti gomina to ṣẹ̀ṣẹ̀ kuro nipo, Gboyega Oyetola ti yan ọba si àwọn ilu naa, paapaa Ikirun, ni ija igboro ti n waye.

O si ti yọrí si ifarapa ọpọ eeyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn dukia si bajẹ.

Rogbodiyan ti n waye lori ọba ni Ikirun ṣaaju asiko yii

Niluu ikirun, ni ọsẹ to kọja, wahala Ọlọbade gba ọna miran yọ lẹyin ti awọn janduku kan ṣe ikọlu si aafin Akinrun ti ilu Ikirun, ti wọn si dana sun un.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe bii osẹ diẹ sẹyin ti awọn eeyan ilu ọhun ṣe ifẹhonuhan lori bi wọn ṣe yan ọba tuntun, wọn gbe adagagodo si ẹnu ọna aafin, eyi ti ko fun Ọba tuntun ni anfani lati wọle si aafin.
Bakan naa ni iroyin ọhun ni awuyewuye miiran bẹ silẹ ni ọsẹ to lọ, lẹyin ti Ọba ati awọn ọlọpaa fẹ wọle si aafin, ti wọn si ṣina bolẹ lati ṣeruba awọn olufẹhonuhan ṣugbọn ti ibọn ba ọkùnrin kan, to si jade laye.
O to eeyan mẹrin miiran to farapa yanayana nigba ti awọn ọlọpaa fẹ gba akoso Aafin naa.

Àwọn àṣẹ míì ti Adeleke tun pa

Yàtọ̀ si ti oyè ọba, Gomina Ademola Adeleke tun pàṣẹ pe owo ko gbọdọ wọlé tabi jade ninu àwọn àsùnwọ̀n ìjọba ipinlẹ Osun.
Bakan naa lo tun wọgile gbogbo igbani ṣíṣẹ́ to waye lẹyin ọjọ kẹtadinligun, oṣu Keje.
Eyi ko yọ àwọn olori ileeṣẹ ati àwọn Àjọ to jẹ ti ìjọba, ti iyansipo wọn waye lẹyin asiko naa, silẹ.