Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti pín l’Osun, báyìí ni ọ̀rọ̀ ṣe di gbas gbos láàrin Aregbesola àti Oyetola

Gomina Oyetola ati Ọgbẹni Rauf

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ó ṣeéṣe kí aáwọ̀ tó wà láàárín Mínísítà fọ́rọ̀ abélé, Rauf Aregbesola àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola túbọ̀ le sii bí Aregbesola ti ṣe làá mọ́lẹ̀ pé ìyapa wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú wọn ní ìpínlẹ̀ náà.

Níbi ìfilọ́lẹ̀ Digital Nigeria Centre (DNC) ní ilé ẹ̀kọ́ Ijesa Muslim Grammar School, Ilesa, Aregbesola ní ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC méjì ló wà ní ìpínlẹ̀ Osun

Ó ní Rasaq Salinsile jẹ́ alága ikọ̀ kan tí Gboyega Famodun sì jẹ́ alága èyí tí ó ń gbè lẹ́yìn Gómìnà Oyetola.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣaájú kí Aregbesola tó gúnlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ náà ní akọ̀wé ìròyìn sí gómìnà, Ismail Omipidan ti sọ lórí ètò kan wí pé Aregbesola kò sí lẹ́yìn àwọn ikọ̀ tí kò tẹ̀lé gómìnà ìyẹn ikọ̀ “The Osun Progressives” (TOP).

Omipidan fi kun un pé àìsí Aregbesola níbi ìpàdé TOP àti ikọ̀ ìpẹ̀tù sááwọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lábẹ́ ìdarí Sénétọ̀ Abdullahi Adamu ti fojú hàn pé kò sí lẹ́yìn wọn.

Ó ní Aregbesola kò sọ́ níbi kankan wí pé òun kò ní ṣe àtìlẹyìn fún ọ̀gá òun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí Aregbesola sọ níbi ètò yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé tí ikọ̀ TOP ni òun ń ṣe àti pé òhun ló ṣe àtiwáyé ikọ̀ tí Salinsile ń darí rẹ̀.

Aṣojú gómìnà níbi ètò náà, Kọmíṣọ́nà fún ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ̀ǹsì, Dókítà Olawale Babatunde ní Aregbesola jẹ́rìí si pé ti ikọ̀ TOP ni òun ń ṣe.

Ó wá pàrọwà sí Kọmíṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun láti ṣòótọ́ nídìí làásìgbò ẹgbẹ́ òṣèlú ìpínlẹ̀ náà.

Aregbesola ní fún ọdún mẹ́jọ tí òun fi ṣe gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun pẹ̀lẹ́ kùtù ni gbogbo nǹkan lọ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ láti ìgbà tí òun ti kúrò.